Okpebolor ni Edo dìbò fún, kìí ṣe Ighodalo… Ìgbìmọ̀

Ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ awuyewuye tó  ṣúyọ látàrí ètò ìdìbò sí ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tó wáyé ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2024 ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ ti Ighodalo àti ẹgbẹ́ PDP pè tako ìjáwé olúborí Monday Okpebolor gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìlú fínnúfíndọ̀ dìbò yàn.

Nígbà tó ń gbé àfẹnukò ìdájọ́  kalẹ̀ lórúkọ àwọn adájọ́ yòókù,Adájọ́ Winfred Kpochi tó lé wájú ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́ta náà ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò fí ẹ̀rí tó dájú gbangba hàn pé lóòótọ́ ni àdìjù ìbò wáyé ní ibùdó ìbò tó tó ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé márún-ún(765 polling units) ninu ibùdó ìbò bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé okòólélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín kan(4,519 polling units) tó wà yíká ìpínlẹ̀ náà.

Ìgbìmọ̀ náà sọ ọ́ yanya pé ó yẹ kí àwọn agbẹjọ́rò PDP, eléyìí tí Agbẹjọ́rò àgbà,Ken Moza kó ṣòdí lè fìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀ nípa pípe ẹlẹrìí tí yóò jẹrìí wọn nítorí ẹ̀rí máa jẹ́ mi nìṣó ni ọ̀rọ̀ ẹjọ́ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ abẹ́rẹ́ ni òkóbó wọn ń bọ̀ dípò ohun tó yẹ kó bọ̀.Ó wá fi ẹsẹ méjèèjì taari éjọ́ náà nù.

Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2024 ni ètò ìdìbò sí ipò gómìnà wáyé ní ìpínlẹ̀ Edo nínú èyí tí Àjọ INEC ti kéde Monday Okpebolor ti inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC gg bíi ẹní tó gbé igbá orókè lêyìn tó ni ibo tó tó Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún- ó-dín-mẹ́sàn-án àti ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ô lé méje(291,667 votes) Nígbà tí Ighodalo ti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìléerúgba ó lé méje àti ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó dín márùn-ún ìbò(247,655 votes)

Èsì ìbò náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pe ẹjọ́ lé lórí pé kò tẹ́ awọn lọ́rùn.Àwọn Òǹwòye òsèlú wá sọ pé Ó ṣe í ṣe kí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sì pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ yìí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×