
Láìfi ti òjò tó ń rọ̀ ṣe, ooru yóò mú púpọ̀ yíká orile-ede Naijiria nínú osù kẹrin tí a wà yìí.Àjọ̀ tó ń wo bí ojú ọjọ́ ṣe rí ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde lójú òpó ìkànnì abẹ́yẹfò twitter rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ti wí,ooru yóò peléké ní ìhà Àríwá tó ìwọ̀n òdiwọn tó wà láàárín ìwọ̀n méjìdínlọ́gbọ̀n sí mejilélógójì (38°c-42°c) Nígbà tí Ààrin gbùngbùn Àríwá yóò gbóná ní ìwọ̀n mẹ́rìndínlógójì sí ogójì (36°c-40°c).Ẹ̀wẹ̀, ìhà Gúsù yóò gbóná ní ìwọ̀n méjìlélọ́gbọ̀n sí méjìdínlọ́gbọ̀n(32°c-38°c)
Bí orú ṣe mú tó ní ìhà kọ̀ọ̀kan ni yóò júwe ewu tó le ṣúyọ látàrí irúfẹ́ ooru bẹ́ẹ̀.Fún àpẹrẹ, àwọn àrùn tó máa ń ṣúyọ látàrí bí ẹ̀fọn bá jẹni bíi ibà yóò wọ́pọ̀ ní ìhà Ààrin-gbùngbùn Àríwá bíi Kwara, Kogi àti Benue nítorí agbára òdì tí yóò gun àwọn ẹ̀fọn.Ní ìhà Àríwá lọ́hùn-ún,ó ṣé í ṣe kí àrùn yínrùnyínrùn tí a mọ̀ sí menigitis ṣe ọṣẹ́
Wọ́n wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n máa mu omi lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lati ṣẹ́gun òrùgbẹ.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
