Tinúbú fún Kyari,Akínyẹ̀lúrẹ̀ ní ìwé Gbélé ẹ

Ilé-iṣẹ́ tó ń mójú tó epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì ní ilẹ̀ Nàìjíríà,tí a mọ̀ sí NNPC ló tí ní àwọn adarí titun bayii.Àwọn náà ni Onímọ̀ ẹ̀rọ Bashir Báyọ̀ Ojúlarí gẹ́gẹ́ bíi olùdarí àgbà àti Ahmad Musa Kida gẹ́gẹ́ bíi alága.

Àwọn wọnyii ní wọ́n yàn dípo Mele Kolo Kyari, tó ti wà ní ipò olùdarí àgbà fún ọjọ́ pípẹ́ àti Paul Akínyẹ̀lúrẹ̀ tó ti wà ní ipò alága láti ọdún 2023.Nígbà tí Adédàpọ̀ Sẹ́gun wọlé gẹ́gẹ́ bii èèkàn kan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀.

Abala kọkàndínláàádọ́ta,ẹsẹ̀ Kejì òfin tó ní nǹkan í ṣe pẹlú ìdáṣẹ́sílẹ̀ àti àtúntò ilé -iṣẹ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ló fún Ààrẹ Tinúbú lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.Bákan náà tún ní wọ́n ṣe ìyànsípò àwọn mẹ́fà mìíràn tí wọ́n ṣojú igun kọ̀ọ̀kan láti igun mẹ́fà tí a pín ilẹ̀ Nàìjíríà sí.

Ààrẹ Tinúbú rọ àwọn ìgbìmò tuntun yìí láti ṣe iṣẹ́ ní ìbámu pẹlú ète ìjọba rẹ̀ láti tún ẹ̀ka náà sọ bíi ẹní ṣọ igbá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ wa yóò fi máa pèsè mílíọ̀nù méjì jálá epo rọ̀bì lóòjọ́ titi ọdún 2027 àti mílíọ̀nù mẹ́ta jálá lójoojúmó títí ọdún 2030.

Bílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún dọ́là ló wọlé sí inú àsùnwòn ìjọba láti ẹka yìí lọ́dún tó kọjá pẹ̀lú àfojúṣùn owó tó tó ọgbọ̀n bílíọ̀nù dọ́là ní ọdún 2027 àti owó tó tó ọgọ́ta bílíọ̀nù dọ́là títí ọdún 2030.Bí ìjọba tí ń ronú owó gọbọi lórí epo rọ̀bì yìí náà ni wọ́n ń reti owó gọbọi láti ìpèsè afẹ́fẹ́ gáàsì.

Bí Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ṣe kí àwọn Ṣẹ̀ṣẹ̀dé Alakoso NNPC kú oríire tí àwọn náà sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti ṣe iṣẹ́ takuntakun láti gbé NNPC gòkè àgbà ló ń kí àwọn tó kúrò nípò kú iṣẹ́ ọpọlọ.Ó sì gbàdúrà fún wọn láti bá ojú rere Ọlọ́run pàdé nínú ìrìnàjò wọn yòókù láyé.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×