Ìjà ńlá bi sílẹ̀ ní Kánò:Wọ́n gún Ẹ̀ṣọ́ Sanusi Pa, Ìjọba fagi lé Ìwọ́de Durbar.

Emir Lamido Sanusi

Ọ̀tẹ̀ òhun dúkùú tó ń lọ lórí ọ̀rọ̀ Emir ní ìlú Kano kàn kú rewé ni ṣùgbọ́n kò kú regbò.Bi kò bá sí pé àwọn òṣìṣẹ́ elétò àbò bá múra gírí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni kò bá di olóògbé nígbà ti Emir Sanusi àti àwọn Abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá sí yídì ọdún àwẹ̀ tó kọjá lọ. yìí.Ọjọ́ àìkú tó kọjá lọ ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní ìlú Kánò.

Ẹ̀ṣọ́ Sanusi kan ní wọ́n gún ní ọ̀bẹ pa tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn sì fi ara pa.Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Kánò ,Abdullahi Kiyawa fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Kiyawa tẹ̀ síwájú pé wọ́n ti ransẹ́ pe àgbà oyè kan Alhaji Wada Isyaku láti wá wí ti ẹnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Lára àwọn tó tún fara pa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni Aminu Sulyman tó jẹ́ ọ̀gá àwọn ìgbìmò figilanté kan ní ìlú náà.Òun àti àwọn mìíràn si ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ nílé ìwòsàn Murtala Mohammed tó wà ní ìlú náà.

Láti dènà irúfẹ́ wàhálà báyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Kánò ti wá fagi lé Durbar tó máa ń wáyé lẹ́hìn ọdún.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×