
Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ídìbò ààrin gbùngbùn Kogi ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà,Sẹ́nétọ̀ Natasha Akpoti Uduaghan ló ṣeéṣe kó kan ìdin ní inú iyọ̀ ,bí èròngbà àwọn ènìyàn ẹkùn ìdìbò rẹ̀ bá wá sí ìmúṣẹ ní bí wọ́n ti ń to orúkọ jọ láti pè é padà wá sí ilé.

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́,ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàléerúgba ó dín mẹ́wàá nínú ẹgbẹ̀rún lọnà ọ̀rìnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àpapọ̀ àwọn Olùdìbò ẹkùn ìdìbò ọ̀hún ni wọ́n ti fi ọwọ́ sí ìwé ìpeniwálé Natasha .
Nígbà tó ń léwájú àwọn ènìyàn tó dìbò náà ní ọọ́fíìsì àjọ tó ń ṣétò ìdìbò ní ilẹ̀ wa tí a mọ̀ sí INEC, Ọ̀gbẹ́ni Salihu Abib fẹ̀sùn ìgbéraga àti àfojúdi tí kò lẹ́gbẹ́ kan Natasha.Ó ní ohun tí wọ́n ní kí òkóbó ó bi, kò bọ̀ ọ́,ó ní òun yáwọ́ abẹ́rẹ́ í bọ̀ ohun tí wọ́n ràn an kó lọ ṣe ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kó ló ń ṣe.Òrìsà bóò le gbè mí, ṣe mí bí ọ ti bá mi.Bí apá kò bá ṣe í sán,a ó káa lé’rí., Fún ìdí èyí, kí Natasha padà wálé kó yèé dójú tì wọ́n.Ó ní iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn agbègbè náà rán òun ni òun ń jẹ́.

Nígbà tí ó ń fèsì,ọ̀gá àgbà kán ní ilé iṣẹ àjọ INEC ti ìpínlẹ̀ Kogi, Arábìnrin Rose Anthony ní ilé iṣẹ INEC ń tẹ́wọ́ gba ìwé ẹ̀ṣùn àti ìdìbò náà ní ìbámu pẹlú abala kọkàndínláàádọ́rin ìwé òfin ọdún 1999.
Bí a kò bá gbàgbé, ilé ẹjọ́ kan ti kọ́kọ́ dá àjọ INEC lọ́wọ́ kọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìwé ìbò ìpeniwálé náà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ẹkùn ìdìbò Natasha ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ gíga mìíràn ti wọ́gi lé àṣẹ náà.
Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe ń lọ yìí,àfàìmọ̀ kí Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ààringbùngbùn Kogi má ṣe kí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Ó dìgbòóṣe.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
