Ó mà ṣe o!Wọ́n jí Àlùfáà Gbé ní Imo

Àwọn Ajínigbé ti gbé àlùfáà ìjọ Àgùdà kan ní Ejemekwuru, ni agbègbè ìjọba Ìbílẹ̀ Oguta, ní ìpínlẹ̀ Imo.Onitọ̀hún ni Àlùfáà Páàdì John Ubaechu ti ìjọ Holly Catholic Church,Ìzombe.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà sẹlẹ̀ ní ọjọ́ àìkú tó kọjá lójú ọ̀nà márosẹ̀ Ejemekwuru.Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn Àlùfáà Páàdì ti ẹkùn Owerri, Àlùfáà Páàdì Patrick Mbarah ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Owerri lọ́jọ́ ajé móńdê ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹta ọdún yìí.

Ààrẹ ẹgbẹ́ àlùfáà Pàádì wá pè fún àkànṣe àdúrá kí Olúwa tètè ṣe ìyọ̀ńda fún Ènìyàn Ọlọ́run náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×