
Gẹ́gẹ́ bí ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó ṣe ń sún mọlé, àwọn àpapọ̀ àjọ tí kò rọ̀gbọ̀kú lé ìjọba ṣùgbọ́n tí gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́ ní wọn rin irin alaafia kaakiri gbogbo ilu Àkúrẹ́ lati ta awọn eniyan jí nipa pataki alaafia pàápàá jùlọ lásìkò àti lẹ́hìn ìdìbò Gómìnà tó ń bọ̀ lọ́nà.
Ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ náà ti ikọ̀ ìròyìn Naija notes Yorùbá bá sọ̀rọ̀, ọ̀gbẹ́ni Táíwò Bólúwatifẹ́ tíì ṣe àkẹ̀kọ̀ọ́ onígbèésẹ̀ kẹta nílé-ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Federal University,Ọyẹ́-Èkìtì sàlàyé pàtàkì Àlàáfíà láwùjọ.

Ó ni kò sí ohun mìíràn ti a le fi we alaafia ni gbogbo aye. Ó wá gba àwọn ọ̀dọ́ ní ìmọràn láti yàgò fún gbígba àwọn Olóṣèlú láàyè láti máa lò wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ohun ètùtù lásìkò ìbò.
Bákan náà ló rọ̀ wọn láti jáde kẹ̀tíkẹ̀tí dibo fún olùdíje tí ó bá wù wọ́n nitori pé ẹ̀tọ́ wọn ni.
Àwọn ọ̀dọ́ náà yan káàkiri awon agbegbe to se pàtàkì pàtàkì niluu Àkúrẹ́.
Ni ọdun 1981 ni ajọ United Nations ya gbogbo ọjọ kọkànlélógún oṣù kẹ̀sán-án odun sọ́tọ̀ gẹgẹ bíi Àyájọ́ ọjọ́ Àlàáfíà lágbàáyé. Àkòrí ayẹyẹ tí ọdún yìí ni Mímú àṣà Àlàáfíà lọ́kùnúnkúndùn

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
