Kàyéfì Ńlá! Ẹni Àádọ́rin ọdún Ń ta Ẹ̀yà Ara Ènìyàn Ni Ìbàdàn

Ọwọ́ pálábá àwọn Amòòkùnsìkà ẹ̀dá tí wọn yan iṣẹ́ òkú wíwú àti ẹ̀yà ara ènìyàn títà láàyò ti ṣégi ní ìlú Ìbàdàn ní bí àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Ọ̀yọ́ ṣe fi kélé òfin gbé wọn tí wọ́n sì ń ṣẹ́jú pàkò lákóló ọba ní ìyágankú

Alukoro ilé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Adéwálé Òsífẹ̀sọ̀ ló fojú ọrọ yìí léde ní olú ilé iṣẹ àjọ Ọlọ́pàá tó wà ní Ìyágankú, Ìbàdàn.

Òsífẹ̀sọ̀ ní àwọn méjì ni àwọn ti gbá mú nítorí olobó tó ta awọn.Nígbà tí àwọn sì dé ilé àwọn ọ̀daràn náà,garawa ọ̀dà ni àwọn bá tí wọ́n kó onírúurú ẹ̀yà ọmọnìyàn bíi apá, agbárí, egungun ẹsẹ̀ àtí bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ sí

Ní kété tí wọ́n mú àwọn ènìyàn burúkú yìí tán ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kà bòòròbò.Lára àwọn tí wọ́n sì kà pé àwọn máa ń ta ẹ̀yà ara ènìyàn fún ni bàbá àgbà tó ti lé ní ẹni àádọ́rin ọdún kan.Wọ́n sì ti di bàbá ọ̀hún ní àpáǹyáká lọ sí olú ilé iṣẹ àwọn ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ìlú kan tó ń jẹ́ Àwà -,Ìjẹ̀bú ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ìjẹ̀bú ní ìpínlè Ògùn ní àwọn tí ń wú àwọn òkú tí wọ́n ń tà náà.

Kọmísánnà Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ògùn,Johnson Adémọ́lá wá jáwé akìwọwọ fún àwọn ọ̀daràn gbogbo kí wọn ó takété si ipinle Ọgun bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò jẹ iyán wọn ní iṣu.

Bakan naa ló rọ awọn ará ìlú kí wọn máa wà ní oju ni alákàn fi ń sọ orí ní gbogbo ìgbà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×