Àkọ̀ròyìn Ilẹ̀ Ghana gba òbìtìbítí owó ìtanràn lórí ẹjọ́ ìbanilórúkọjẹ́ tó pe Olóṣèlú ilẹ̀ náà kan

Anas Aremeyaw

Ògbóhùtarìgì akọ̀ròyìn tó máa ń fi irun bójú fín àwọn Amòòkùnsìkà lápe ní ilẹ̀ Ghana nnì,Anes Aremeyaw ni ilé ẹjọ́ kan ní ilẹ̀ America ti pàṣẹ fún pé kó gba  mílíọ̀nù méjìdínlógún dọ́là owó ìtanràn  lọ́wọ́ àgbà òṣèlú kan tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Ghana , ìyẹn Kennedy Agyapong gégé bíi owó ìtanràn .

Anes Aremeyaw ló wọ́ Kennedy Agyapong gẹẹrẹgẹ lọ sí ilé ẹjọ́ látàri ẹ̀ṣùn ìbanilórúkọjẹ́ ní ọdún 2021. Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́, Aremeyaw ló ṣe iṣẹ́ ìwádìí kan nínú èyí tó ti tú àṣírí ìwà jẹgúdújẹrá kan ti olóṣèlú yìí hù. Ọ̀rọ̀ náà bí olóṣèlú yìí nínú tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Aremeyaw lori ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan lórí Tẹlifísàn.

Aremeyaw kò bèṣùbẹ̀gbà,ó kọrí sí ilé ẹjọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó sì pe Agyapong ní ẹjọ́,ó fi ẹ̀ṣùn ìbanilórúkọjẹ́ kàn án.Ọ̀ṣẹ̀ yìí sì ni Adájọ́ tóo dá ẹjọ́ náà nínú èyí tí ó ti dájọ́  pé kí Agyapong lọ san mílíọ̀nù méjìdínlógún dọ́là gẹ́gẹ́ bíi owó ìtanràn fun Afimúfínlẹ̀ Oníròyìn náà.Ẹ̀ẹ̀kejì rèé ti Aremeyaw yóò pe ẹjọ́ ìbanilórúkọjẹ́ tako àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú.Eléyìí tó kọ́kọ́ pè sí ilé ẹjọ́ kan ní ilẹ̀ Ghana kò ṣo èṣo rere nítorí wọ́n da ẹjọ́ náà rú.Ìdí sì rèé tó fi forí lé ilẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà tí ẹlẹ́ẹ̀kejì yìí tún ṣẹlẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ náà, Aremeyaw ní òun kò ní ṣìn lẹ́yìn àwọn Jẹgúdújẹrá olóṣèlú titi tí ilẹ̀ Ghana yóò fi dùn-ún gbé fún tẹrútọmọ. Ó kókè ìdájọ́ òdodo ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ilẹ̀ Ghana náà yóò dé ìpele ìdájọ́ òdodo báyìí bi àwọn ènìyàn kò bá sinmi láti máa gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×