
Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Bọ́lá Tinúbú ti yan Ọ̀gàgún fẹ̀hìntì ojú omi Ibok Ette Ibas gẹ́gẹ́ bíi Alákòóso ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers.
Eléyìí ló wáyé nítorí ìjọba Pàjáwìrì tí Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú gbé kalẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Rivers látàri kọ̀bàòle òsèlú tó gba ipinlẹ̀ náà kan tí eku kò ké bí eku mọ́ tí ẹyẹ kò si dun bí ẹyẹ mọ́.
Ètò ìsàkóso ìjọba ọkùnrin yìí ní yóò máa tẹ̀lé òfin ṣùgbọ́n kò nílò ìfọwọ́sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin kó tó di pé ó náwó.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé àwọn ìgbésẹ tó bá lágbára tó bá fẹ́ gbé kò lè wáyé láìjẹ́ pé ó gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ìgbìmò alákòóso ìjọba àpapọ̀.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
