Alukoro Ẹgbẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ANBROAD;Kẹ̀kẹ́ Àwàdà Gba Àmì Ẹ̀yẹ

Ògbóhùntarìgì Afèdèsẹṣọ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ nnì, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ si Kẹ̀kẹ́àwàdà, Ọ̀gbẹ́ni Adékúnlé Adéwùmí tíí ṣe Olùdarí ilé iṣẹ́ kẹké Àwàdà Media Network ni ilé iṣẹ́ Face of African TV ti fi àmìn ẹ̀yẹ̀ Èèkàn òhun Kòṣeèmọ́nì-ín nínú iṣẹ ìròyìn àtìgbóhùnṣáfẹ́fẹ́ dá lọ́lá.

Ọjọ́ Sáńdè tó kọjá ni ayẹyẹ náà wáyé ni Sunbeth Hotels,Síjúadé, Àkúrẹ́. Nínú ọ̀rọ̀ àwọn aláṣẹ Face of African TV,wọ́n ṣàpèjúwe Adéwùmí gẹ́gẹ́ bíi Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó mọ èdè òhun ẹ̀yọ̀ ,ó dáńtọ́,Ọ̀mọ̀ràn tíí moyún ìgbín nínú ikarahun ní í ṣe tó bá di ká ṣètò tó ń kọ́ni lọ́gbọ́n,kọ́ni lóye lórí afẹ́fẹ́ .

Nígbà tí ó ń fèsì, Adéwùmí dá gbogbo ògo padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.Ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti tiẹ̀ síwájú nínú ohun gan -an ti Face of African TV rí nínú iṣè òun ti wọ́n fi dá òun lọ́lá.Ò fi àwọ́ọdù ọ̀hún ṣe ìmọyì fún bàbá òun,Alàgbà David Adéwùmí tó ti di olóògbé.

Ó ti lé ní ogún ọdún tí Adékúnlé Adéwùmí ti ń ṣe iṣẹ́ ìròyìn àti ìgbóhùnṣáfẹ́fẹ́.Ò  ṣe iṣẹ́ ní Àdàbà fm, Àkúrẹ́ kó tó kọ̀wé fi ipò silẹ̀. Ní báyìí, kò dín ní ilé iṣẹ́ Rédíò mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yíká ìpínlẹ̀ Oǹdó tó ti ń ṣètò orisirisi lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Òun ní Alukoro Ẹgbẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ANBROAD ní ìpínlẹ̀ Oǹdó

Lára àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn àwùjọ ti àwọn náà gba àmì ẹ̀yẹ níbẹ̀ ni Họnọrebu Ẹníkù Ọmọ́tàyọ̀, Agbẹjọ́rò Olúmúyìwá Adú tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Kùbànà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×