Ẹ lọ gbé Adájọ́ àgbà tìmọ́lé: Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Rivers pàṣẹ fún Ọlọ́pàá

Adájọ́ Àgbà Simeon Ajadi

Bí ẹ̀ṣùn tí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers fi kan Adájọ́ àgbà ní ìpínlẹ̀ náà pé ó yí ọjọ́ oríire rẹ̀ pẹ̀lú ète àtifìdípagbá sidìí iṣẹ́ ìjọba bá jẹ́ òdodo tí kìí bá ṣe ọ̀rọ̀ òṣèlú;a jẹ́ pé ewu ń bẹ lóko Lóńgẹ́ orilẹ ede yìí nínú ètò ìdájọ́ wa.Tí ìdájọ́ òdodo tíì ṣe ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ fún ìjọba tó jíire bá sì ti mẹ́hẹ,ó dájú pé gbogbo ẹ̀ka yòókù náà ló ti wọ gàhù!

Wọ́n ti ní kí wọn ó ṣe ìwádìí rẹ̀, kó sì yẹ̀bá lórí àga ná títí ti èsì ìwádìí náà yóò fi fojú lède.

Bákan náà ni ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin lábẹ́ ìdarí Họnọrèbù Martins Amaewhule pàsẹ’Bọ́-síbí-kóo-wá-wí-tẹnu-rẹ’ òníwákàtí méjìléláàádọ́rin fún Adájọ́ Adolphus Enebeli láti wá sọ ohun tó rí lọ́bẹ̀ tó fi waro ọwọ́ lórí bó ṣe tàkìtì ìpàkọ́ sí àṣẹ ilé ẹjọ́ tó sọ pé kò gbọdọ̀ ṣètò ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀, eléyìí tó wáyé lábẹ́ ìsàkóso rẹ̀ ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá ọdún 2024.

Bí Adájọ́ Enebeli ṣe sánpá Tańkù sí àsẹ ile igbimo asofin pẹ̀lú bí kò ṣe yọjú ló fà á tí ilé -ìgbìmọ̀ asofin fi ní kí wọn ó fi kélé òfin gbé e nítorí ẹni tó bá ní ‘Kín laá ṣe?Ni àá ṣe é hàn’

Bí a kò bá ní gbàgbé, Gómìnà Siminalaye Fubara ti pinnu láti mú gbogbo àkóónú  àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ṣẹ láìkù kan.Lára àṣẹ náà sì ni wíwọ̀gi lé ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé nínú oṣù kẹwàá ọdún tó kọjá,títún àbá ètò ìṣúná ọdún 2025 gbé fún ilé ..abbl

Lẹ́yẹ-ò-sọkà sì ni Gómìnà ọ̀hún sì ti ń mú àṣẹ náà ṣẹ, pàápàá jùlọ bí ó ti ṣe kọ ìwé sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣugbọn ti àwọn onitọ̀hún kò jẹ́ kó wọlé sile igbimo náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×