
Bí àrà ni ìbọn ṣe ń dún tí èèfín si sọ ojú ọ̀run di dúdú bí aró ni agbègbè Zuman Bread ni ìlú Chaichainiya tó wà ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Suleja ni ìpínlẹ̀ Niger .Ní déédéé agogo mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kí ìrun Aṣámú tán lánà-án ọjọ́ jímọ̀ ní Kọ̀bàòlé ọ̀hún wáyé.
Onímọ̀ nípa ètò àbò kan tí ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀,Zagazela Maikama ṣàlàyé pé ọmọkùnrin kan tó wà ní igbéṣẹ̀ tó kẹ́yìn ní ilé ìwé girama Annur Islamic Model School,Umar Idris ló kó àwọn ẹrú ikú bíi ogún wọlé láti wá ṣẹ̀rù balẹ̀ lẹ́hìn tí èdè àìyedè kan lórí ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó fura sí pé àwọn ọ̀dọ́ agbègbè náà kan ń dà láàmú ti wáyé .
Láti fi àjùlọ hàn gẹ́gẹ́ bíi ọkọ ìyàwó ló fí kó àwọn ọmọ gànfé náà lẹ́hìn láti síná ìbọn bolẹ̀ . Bí àwọn ikọ̀ Idris Umar kò ṣe wọ̀n ọ́n kún,ni àwọn tí wọn wá bá náà kò gbà á láàbọ̀ tí tọ̀tún-tòsì sì ń dáná ìbòn yá ara wọn titi ti àwọn kòmọwọ́-mẹsẹ̀ méjì;Immam Hassan ọmọ ọdún mẹ́wàá àti Nura Jibrin ẹni ọdún mọ́kànlá fi gbàlejò ọta ìbọn lára kóówá wọn, eleyii tó fà á tí wọ́n fi dèrò họsibítù Gẹ́nẹ́rà ti ìlú Suleja.
Àjọ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger ti mú àwọn Afurasí mélòó kan lórí ọ̀rọ̀ náà wón sì fi kún un pé ìwádìí tó lọ́ọ̀rìn ti ń lọ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!

Mo dupe gidigidi lowo o re fun igbe laruge ede Yoruba. Wa a se aseyori ooo