Ìdàgbàsókè ìjọba Ìbílẹ̀ Òkìtìpupa ló jẹ mí lógún..Ọ̀gúnṣakin

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa,Họnọrèbù Andrew Ògúnṣakin ti sàlàyé bí ìdàgbàsókè ìjọba Ìbílẹ̀ Òkìtìpupa ṣe jẹ ẹ́ lógún sí àti bó ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà láti fọwọ́ ṣọwọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ rẹ̀ láti mú kí àlá rere tí ó ní fún ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa wá sí ìmúṣẹ.

Ògúnṣakin fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń ṣe ìpàdé àkọ́kọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alákòóṣo ìjọba ìbílẹ̀ náà tí olórí àwọn òṣìṣẹ́,Ọmọọba Ọjọmọ kó ṣòdí.

Ó kọminú sí ìhà tí àwọn ènìyàn ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa kọ sí ìmọ́tótó àyíká wọn nítorí àyíká tó mọ́ ló ń ṣe atọ́kùn fún ìlera;òhun kan náà ló lè ṣẹ́gun àrùn gbogbo.Ó rọ àwọn òṣìṣẹ́ ètò àyíká láti jáwé sóbì iṣẹ́ wọn láìfọ̀tá pè.

Alága tún korò ojú sí ipò tí kò bójú mu tí àwọn ọọ́fíìsì gbogbo wà.Ó wá se ìlérí pé gbogbo ọọ́fíìsì ní òun máa tún ṣe láti mú kí iṣẹ́ rọrùn. Ó tẹ̀ síwájú pé láìpẹ́,iná mọ̀nàmọ́ná yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ nínú ọgbà Sẹkitéríàtì.Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ ilégbèé fún àwọn lọ́gàálọ́gàá òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Bí Awo bá kì fúnni,a ń kì fún Awo padà ni.Nígbà tó ń fèsì,Olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa,Ọmọọba Ọjọmo kí Alága kú oríire fún bí ó ti jáwé oluborí nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó kọjá lọ.Ó sì dúpẹ lọwọ alága fún níní èròngbà rere láti ṣe iṣẹ́ sin àwọn ènìyàn rẹ̀.Lẹ́yìn èyí ló wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ àtìlẹ́yìn àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa fún alága .

Àáyá bẹ́ sílẹ̀,ó bẹ́ sáré ni Ògúnṣakin fi ọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ṣe, nítori ní kété tí ìpàdé parí ni Òun, àwọn ọmọ ìṣèjọba rẹ̀ àti àwọn Olùdarí lẹ́lẹ́kaǹka rìn yíká ọgbà náà láti wo pàtó ibi tí iṣẹ́ yóò ti bẹ̀rẹ̀.

Lára àwọn tí wọ́n wà nínú ìpàdé náà ni Igbákejì Alága, Họnọrèbù Orímisàn Ògúnyẹmí,Akọ̀wé ìjọba ìbílẹ̀, Amòfin Fẹ́mi Ọládòkun, àwọn olórí ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan,Àyẹ̀wé-owó -wò fún ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa, Alukoro Ìjọba ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×