Ní ìpínlẹ̀ Rivers: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní ìwé Gbélé ẹ

Ní òjijì ni jàgínníyòdò àwa la wà ní ìjọba awọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers di ìbànújẹ nígbà tí ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ ní ilẹ wa da èrùpẹ̀ sí gàárì wọn pẹ̀lú bi ó ti dá ẹjọ́ pé kí wọn ó gba ilé wọn lọ.

Ọjọ́ jímọ̀ ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejì ọdún yìí ni ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ tí Adájọ́ Uwani Abba-Aji kó ṣòdí fẹnu kó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé àjọ elétò ìdìbò ipinlẹ Rivers kò lẹtọ láti di ibò náà rárá pẹ̀lú àṣẹ tí ilé ẹjọ́ àwọn ti kọ́kọ́ pa sáájú pé àjọ INEC kò gbọdọ̀ fún RSIEC ní ìwé àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn olùdìbò,síbẹ̀ àjọ RSIEC tẹ̀ síwájú láti ṣe ètò ìdìbò náà.

Adájọ́ Jaminu Tukul tó gbẹnu àwọn adájọ́ yòókù se sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ pé òtúbáńtẹ́,fùlùfúlù àti aásà tí kò ní kàn-ún ni ìdájọ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ẹkùn Abuja tí ó dá ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kọkànlá ọdún 2024 pé kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ náà máa gẹsin lọ nínú ọlá ńlá wọn .

Adájọ́ Jaminu Tukul ní gbogbo ìlànà ìdìbò náà tako abala àádọ́jọ ẹsẹ̀ kẹta òfin ètò ìdìbò ọdún 2016.Ó wá ní ìjọba Àpapọ̀ kò gbọdọ̀ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Rivers lówó mọ́ titi tí àṣẹ mìíràn yóò fi jáde lórí ìdájọ náà.

Nígbà tí ó ń bá àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Rivers sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ náà lórí ẹ̀rọ agbagbe lọ́jọ́ àìkú ọjọ́ kejì oṣù kẹta ọdún yìí, Gómìnà Siminalaye Fubara pàṣẹ kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ yíká ìpínlẹ̀ náà fa ètò ìṣàkóso lé olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ kóówá wọn lọ́wọ́ lónì-ín ọjọ́ ajé ọjọ́ kẹta oṣù yìí títí tí ètò ìdìbò mìíràn yóó fi wáyé.

Ó wá rọ àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ náà láti wọn ṣe jẹ́ẹ́! Bi-o-tilẹ̀-jẹ́-pé ìdájọ náà kò tẹ́ wọn lọrùn,síbẹ̀, kò sí ẹni tó lè fi ọwọ́ pa idà òfin lójú .

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×