
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí a tí ń pa ọ̀kan ni ọkan ń rú ni ilé-ìfọpo Dangote nitori ogun tó gbé tí Ọkùnrin pàràkòyí ìṣòwò náà kìí ṣe kèrémí bayii pàápàá jùlọ láti ọ̀dọ̀ àwọn Alágbàtà Epo ti wọ́n ti tún forí lé òkè òkun láti lọ ra epo rọ̀bì dípò kí wọ́n rà á lábẹ́lé.
Ọ̀kan lára àwọn àgbà òṣìṣẹ́ ilé -iṣẹ́ yìí tó ní ká fi orúkọ bo òun lásìírí ló fojú òrò yìí lédè nílùú Èkó. Gẹ́gẹ́ bó ti wí,ó ni àkóbá ńlá ni irú igbésẹ̀ yìí yóò fà fún ọrọ̀ ajé Naijiria pẹ̀lú ipò fòní-kú-fọ̀la-dìde ti owo Náírà wà.
Ó fi ẹ̀ṣun kan àwọn Alágbàtà Epo pé àwọn epo tí wọn ń kó wọlé láti ilẹ òkèèrè kò mú yányán tó lójúnà àtijèrè àjẹpajúdé láìro ewu tí ìrú ìgbésẹ bẹ́ẹ̀ le fá fún àwọn tó n ra epo. Ó tẹ̀ síwájú pé ilé-Ìfọpo Dangote kún ojú òṣùwọ̀n láti pèṣè epo tó tó lò lábẹ́lé.
Nigba tó ń kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn,Akọ̀wé ìkéde Ẹgbẹ́ Olùfọpo rọ̀bì tí a mọ̀ sí CORAN ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Ògbéni Eche Idoko ní ẹ̀rù àìṣórogún eleyii tó lè fa àṣilò agbára láti ọ̀dọ̀ Dangote ló n ba àwọn Alágbàtà náà lẹ́rù Ó wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé òfin àti ìlànà ìdásílẹ̀ ilé -iṣẹ́ ìfọpo náà kò lè fi ààyè gba irúfé ìjẹgàba bẹ́ẹ̀.
Gbogbo akitiyan wa láti bá alága Alágbàtà Epo sòrò ló já sí pàbó nítorí ó kan láti gbé agogo tàbí fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
