Ẹ jọ̀wọ́, Níbo ni Àjọ Road Safety Wà o?

Bí ènìyàn bá rí bí àwọn ọkọ̀ ṣe ń di ẹrù ní ìdìkudì ní ọ̀nà Òkìtipupa sí Ọ̀rẹ̀, àánú ọkọ̀,ọlọ́kọ̀,ọ̀nà tí wọn ń tọ̀ àti àwọn yòókù tó ń lo ojú pópó yóò ṣe ènìyàn nitorí bí ènìyàn bá rí gẹ̀gẹ̀sì àyà ìmọ̀dò níbi tó ti ń pa ìgbín ká igbó yóò mọ irúfẹ́ ewu tó ń bẹ lórí Ahun.Ohun mìíràn tí ènìyàn yóò tún rò ní pé bóyá àwọn òsìṣẹ́ àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó tí a mọ̀ sí Federal Road Safety Officers ti gba ìsinmi ni, ṣùgbọ́n rárá o!Wọ́n kúkú wà lẹ́nu iṣẹ́,tí wọ́n dúró sí títì ti wọn ń gba rìbá lọ́wọ́ àwọn onímọ́tò ẹlẹ́rù sìm̀biri náà láìnáání ewu tí irúfẹ́ ìwà ìbàjẹ́ náà lè fà fún àwọn tó ń lo ojú pópó.

Ti àwọn Ọlọ́pàá la rí tí a ń wí, tí àjọ Road Safety kọyọyọ.Ẹ̀tẹ̀ ni wọn á fi sílẹ̀ tí wọn yóò máa pa làpálàpá.Ohun tí a ní kí òkóbó wọn bọ̀, kò bọ̀ ọ́,igba abẹ́rẹ́ ló ní òun le bọ̀ lóòkùn . Àwọn ọlọ́kadà àti ọkọ̀ Aládàáni ló dáràn lọ́wọ́ wọn.Àkùkọ wọn ti fi ogbe orí rẹ̀ fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ṣeré.Wọ́n ti ṣo yangan mọ́ ìdí,wọ́n ti di ojúgbà adìrẹ.

Àsìkò sì wà fún wọn láti ti tún èrò ọkàn wọn pa kí wọ́n má ṣe jẹ́ oríṣun ewu fún àwọn tó ń lo ojú pópó.Kí wọn máa gbìyànjú láti lo òfin ojú pópó bí ó ti tọ́ fún gbogbo onípòjipò láìṣègbè .

Kí wọ́n ta kété sí owó kọ́bẹ́ tó ń mú wọn díjú sí ìwà ìbàjẹ́ àwọn onímọ́tò.

Ki àwọn onímọ́tò náà yàgò fún ìwà ọ̀kanjúà nípa didi ẹrù àdìjù lé ọkọ̀ wọn lórí .

Bóyá ni àwọn onímọ́tò pàápàá mọ̀ pé ó níwọ̀n ẹrù tí agbára mọ́tò kọ̀ọ̀kan gbé.Gbígbé kọjá ẹrù tí mọto lè rù máa ń fa ìpalára fún irúfẹ́ ọkọ̀ bẹ́ẹ̀.Kí wón má gbàgbé láti máa yẹ àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀ wọn wò lóòrèkóòrè

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×