Alága di Méjì ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ọ̀kan ń ṣe ilé,Ìkejì Ń Ṣe ìjọba.

Lẹ́yìn ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ yíká ipinlẹ Ọ̀ṣun tó wáyé ní ọjọ́ Sátidé ọjọ́ kejìlélógún oṣù kejì ọdún yìí níbi tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti jáwé olúborí ní gbogbo Wọ́ọ̀dù àti ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n ní ìpínlẹ̀ náà ; ti Gómìnà Adélékè sì ti búra fún wọn ní ọjọ́ àìkú àná tíí ṣe ọjọ́ kẹtàlélógún, Gómìnà fúnra rẹ̀ ti pàṣẹ pé kí oníkálukú jókòó sí ilé rẹ̀ ni oo.Ó ni wọn kò gbọdọ̀ dé káńsù rárá .

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti pàṣẹ pé kí àwọn alága ìbílẹ̀ tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ìlú Àkúrẹ́ dá padà sí orí àlèéfà lọ wọlé sí ibi iṣẹ́ wọn ní òní ọjọ́ ajé.

Àtẹ̀jáde náà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ gànfé ki wọ́n takété sí ìjọba ìbílẹ̀ nítorí wámú ni àwọn agbófinró yóò wà níkàlẹ̀ láti jáwé akìwọwọ fún alétílápá ẹ̀dá.

Nígbà tí ilé ẹjọ́ tí sáájú dá àwọn alága kan padà, tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun sì tẹ̀ síwájú láti búra fún àwọn mìíràn lẹ́yin tó dìbò tán; tí ó wá fúnra rẹ tún pàṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ wọlé sí ibi iṣẹ́ wọn.Kín wà ní ìtumọ ìbò tí wọ́n dì nígbà náà?

Ìwé ìròyìn Naija notes Yorùbá kó ní jẹ́ kí etí yín dì sí bí ọ̀rọ̀ náà bá ti ń lọ

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×