Atáyérọ bí Agogo ni Ayọ̀ Adébánjọ…..Fáṣọ̀ràntì

Olórí káààfàtà fún ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re,Bàbá àgbà Reuben Fáṣọ̀ràntì ti ṣàpèjúwe olóògbé Samuel Ayọ̀dèjì Adébánjọ gégé bíi ọlọ́pọlọ pípé,àgbà óṣèlú àti Awíkonko lójú ọlọ́rọ̀.

Àná ni Fáṣọ̀ràntì sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí àwọn ọmọ Yorùbá àti ìdílé Olóògbé Ayọ̀ Adébánjọ tó di olóògbé lánà-án.

Baba ní ikú Adébánjọ dun òun jọjọ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò ní dunni kí ojú rẹ̀ ó bù.Ó wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tu àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé nínú.

Ayò Adébánjọ ni ìròyìn ikú rẹ̀ tàn kálẹ̀ lánà-án lẹ́yìn tí ó jẹ́ Ọlọ́run nípè wọ́ọ́rọ́wọ́ nílé rẹ̀ tó wà ní ojúlé kẹjọ, agbêgbè Ayọ̀ Adébánjọ Lekki phase 2 ní ìlú Èkó.

Èèkàn nínú ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ni Ayọ̀ Adébánjọ nígbà ayé rẹ̀.Òun sì ni igbákejì Bàbá àgbà Reuben Fáṣọ̀ràntì tíí ṣe alága ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re báyìí.

Ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni bàbá náà lò láyé kí ikú tó pa ojú rẹ̀ dé.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, ọmọ -ọmọ àti ọmọ-ọmọ-ọmọ ló gbẹ̀yìn bàbá náà

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×