
Olórí ẹ̀ka kan nínú Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Àlà gbà Ayọ̀ Adébánjọ ti di olóògbé.Kùtùkùtù Òwúrọ̀ òní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún 2025 yii ló jẹ Ọlọ́run nípẹ̀ ní ilé rẹ̀ ní ojúlé kẹjọ agbêgbè Ayọ̀ Adébánjọ,Keji phase 1, ní ìlú Èkó ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún.
Ọdún 1928 ni bàbá tọ́ omi ayé wò ní Ìsányà-Ôgbó nítòsí Ìjẹ̀bú-Òde, Ìpínlẹ̀ Ògùn
Àgbà ọ̀jẹ̀ Olóṣèlú ni Ayò Adébánjọ nígbà ayé rẹ̀.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ọmọlẹ́yìn Awólọ́wọ̀ ni í ṣe,ọ̀dọ̀ Nnamdi Azikiwe ló ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèlú ní ọdún 1943.
Lára àwọn tó gbẹ̀yìn rẹ̀ ni aya rẹ̀ Christy tíì ṣe ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rûn-ún, àwọn ọmọ, ọmọ-ọmọ àti omo-omo-ọmo.
Nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ Mọ̀lẹ́bí olóògbé ló ti hànde pé wón ti sí ìwé ìbánikẹ́dùn sí ilé rẹ̀ ni Lekki ati Ïsányà -Ògbö

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
