Ìyànjẹ Ńla! Wọn ta Ọmọ ní Mílíọ̀nù Mẹ́rin Náírà,Wọ́n fún ìyá ní Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ẹgbẹ̀ta Náírà

Abilékọ ẹni ọdún mẹ́rìnlèlógún kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Racheal tó fi ìlú Asaba ní ìpínlẹ̀ Delta ṣe ibùjókòó ti sọ pé òun ta ọmọbìnrin òun tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọ̀ṣẹ̀ méjì lọ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta náírà nítorí pé òun kò ní agbára tí òun yóò fi tọ́ ọ lẹ́hìn tí baba ọmọ náà ti fàáké kọ́rí pé òun kò lòun loyún ọmọ náà.

Ẹ̀wẹ̀, ẹni tó ra ọmọ ní Mílíọ̀nù Mẹ́rin Náírà ní òun sàn fún ọmọ náà lọ́wọ́ Oníbàràǹdà tó gbé ọmọ náà wá sí ọ̀dọ̀ òun.

Àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Delta ló fojú Racheal léde àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ọ̀daràn mìíràn ní olú ilé iṣẹ àjọ Ọlọ́pàá tó wà ní ìlú Asaba.

Racheal ní ọmọ méjì ni òun bí: Ọkùnrin kan àti obìnrin kan.Ṣùgbọ́n nígbà tó hàn gbangba pé agbára òun kò gbé àtibọ́ wọn mọ́ ní òun fi ta èyí obìnrin tí òun bí ní ọjọ́ ketadinlogbon, oṣù kìíní ọdún yìí .

Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí ọ̀nà tó gbà tó fi tọ́jú oyún nígbà tí kò sí ọkọ,Racheal ní kò sí iṣẹ́ tí òun kò ṣe tán bíi ká ru bíríkì, ká báni gbálẹ̀-fọṣọ..abbl.

Lórí ọ̀rọ̀ bí ọmọ ṣe di títà,Ó ní òun bá ìrànwọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Arábìnrin ẹni ọdún mejilélógójì kan ẹni tó fi ọmọ títà lọ òun,Akáyín ṣé wàá jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀? Ó ní ‘kín ni a gha ń ghá?’ ní ọ̀rọ̀ ọ̀hún jẹ́ nítorí òun ti rò ó pin.Àìlówó láti gbọ́ bùkátà ló ti òun si ìwà aburú náà.

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta ( ₦600,000) ló fún mí o.Ó sì tún ní kí n settle òun nínú rẹ̀.Mo sì fún ùn ní Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (₦30,000) nínú r’oko Racheal ló ń sọ̀rọ̀ báyìí.

Ní ti ẹni tó ra ọmọ,ọ ní àgbàwò ní òun ni lérò láti ṣe kìí ṣe pé òun ra ọmọ.Ó tẹ̀ síwájú pé gbogbo ìwé tí yóò jẹ́rìí ọ̀rọ̀ òun ti fẹ́rẹ̀ parí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×