Ó ga o! Àwọn Ènìyàn Mi Kò Mọ Rírì Mi….Pọ́tébù

Ẹni tí a fẹ́ tí kò fẹ́ràn ẹni,àtàtà àdánù ni Yorùbá pè é. Òṣónú ilé kò sì gbọ́ ààlọ̀,ààlọ̀ kò ran ẹni tí kò fẹ́ràn ẹni.Àwọ́n gbólóhùn kàǹdùkàǹdù yìí ló ń jáde láti ẹnu Olórin Ṣèwọ́ṣèwọ́ ti ẹnu kìí sìn lára rẹ̀ bí Afọ́’kèéèmù nnì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Pọ́tébù.

Ṣé bí kò bá nídìí obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú, Ọ̀rọ̀ kan la sì máa ń sọ dé ibi “Oko Àwé rèé” Ohun tó fa ìdí abájọ ni kọ̀bàòle tó wáyé láàárín Olórin náà àti àwọn òsìṣẹ́ Olówóorí ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn tí wọ́n fi ẹ̀ṣùn kan olórin náà pé ńṣe ló fi ìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n wá gba owó orí sọ́ọ̀bù ibí tó ti ń ta ọtí.Kànràn kí Pọ́tébù san owó gégé bíi Ọmọlúwàbí, ṣe ló tutọ́ sókè tó fojú gbà á ,bẹ̀rẹ̀ sí ní bá wọn jà, bó ti ń bú Ọpa ló ń bú Sàngó;tó ń kanra mọ́ wọn bí ajá elékùúkú.Ìhúwàsí rẹ̀ yìí ló sì mú kí àwọn onítọ̀hún kúkú gbé sọ́ọ̀bù rẹ̀ tì pa.Ṣé Agbèfọ́ba kìí jẹ̀bi.

Ẹ̀wẹ̀,nígbà tí ọmọ Ọlálọmí ń sọ̀rọ̀,ó ní ẹ̀tanú òun ní àwọn Agbèfọ́ba náà ń ṣe nítorí òun kò tilẹ̀ sí ní sọ́ọ̀bù nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.Ó ní ” Ojú oorun ni mo wà lọ́sà-án ọjọ́ náà.Wọn kò tilẹ̀ dúró kí n yọjú sí wọn tí wọn fi gbé sọ́ọ̀bù tì.Èyí jẹ́rìí sí í pé wọ́n ń bínú ọmọ ológo ni oo.Ó dùn mí pé àwọn ènìyàn mi ní ìpínlẹ̀ Ògùn kò mọ iyì mi.” Pòròpòrò ni omi ń bọ lójú àgbà olórin náà bíi tóóto bí ó ti ń sọ ọ̀rọ̀ náà.Ó wá pàrọwà sí ìjọba kí wọ́n jọ̀wọ́ jàre sí sọ́ọ̀bù òun padà nítorí ní inú ilé tí sọ́ọ̀bù náà wà ni òun ṣin ìyá òun tó ti kú nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlàá sí.

Àtẹ̀jáde kan láti ọ́ọ́fíìsì Olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Káyọ̀dé Akínmádé sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti jáwé akìwọwọ fún Pọ́tébù kó yèé ṣe gàlègàlè mi kó yan ìwà Ọmọlúwàbí láàyò.,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóò rí pípọ́n ojú ìjọba.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×