Ní Zamfara,Ìjàm̀bá Iná Gba Ẹ̀mí Ọmọ Ilé Kéú Mẹ́tàdínlógún

Kò dín ní ọmọ ilé Kéú Mẹ́tàdínlógún tó jẹ́ Ọlọ́run nípè láìròtẹ́lẹ̀ nínú ìjàm̀bá iná tó sọ ilé ẹ̀kọ́ kéú kan tó wà ni Kaora-Namoda ní ìpínlẹ̀ Zamfara di ahoro ní òru ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí.

Òru ọ̀gànjọ́ ni iná déédéé ṣẹ́yọ nínú ọ̀kan lára àwọn yàrá ilé ẹ̀kọ́ náà.Kí olójú tó ṣẹ́ ẹ pẹ́ẹ́; iná ọ̀hún tí sọ ara rẹ̀ di orin àkọgbè yíká àgbègbè ilé ẹ̀kọ́, eléyìí sì jẹ́ kó nira fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọ́n wà lójú oorun láti lè sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Kí ó tó di pé àwọn Panápaná dé, kò dín ní ọmọ ilé Kéú Mẹ́tàdínlógún tó ti jẹ́ Ọlọ́run nípè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fara pa yánnayànna.

Óṣojúùmipàtó kan, Ibrahim Nasir fi yé wa pé òru tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ló fà á tí ààyè fi gbà á tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ tẹ̀mí-ti-dúkìá run lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bẹ́è.Tó bá jẹ́ ọ̀sàn gangan ni,Nasir ní àwọn ènìyàn kì bá tètè sa ipá láti pa á, ṣùgbọ́n ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èrò ló ń sùn lọ́wọ́ nígbà tí làlúrí náà sẹlẹ̀.

Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Zamfara ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti mọ ohun tó fa ìjàm̀bá náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×