Bí Ààrinọlá Abraham Love bá wẹ ọsẹ àwúre èpè, Àwúre náà kò le fa òbítíbitì èpè tó èyí tó fi tẹ̀fọ́tí-tẹ̀fọ́tí òhun ìdọ̀bálẹ̀ gbọọrọgbọ bìí Aláǹgbá gbà lẹ́nu Ọba Sẹ̀míù Ògúnjọbí,Orílé ti ìlú Orílé-Ifọ̀ ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ifọ̀ ní ìpínlẹ̀ ògùn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí láàfin Kábíyèsí náà.

Ẹ̀rọ fidẹó fán-án-rán òníṣẹ̀ẹ́jú méjì kan tó ṣàdéédé di tọ́rọ́fọ́nkálé lórí ẹ̀rọ Ayélujára ló ṣe àfihàn Ọba Sẹ̀míù Ògúnjọbí tó ń rọ́ ikin èpè lé orí Ààrinọlá Abraham lórí ẹ̀ṣùn pé ó dalẹ̀ Ṣùgbọ́n tí ẹni àfẹ̀ṣùnkàn takú wọnnle pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
Bí Baálẹ̀ náà ṣe ń ṣẹ́ ẹ̀ṣùn ọ̀hún tó;ẹ̀yìn etí Kábíyèsí ló ń bá lọ.Bí Ọba Sẹ̀míù Ògúnjọbí ṣe ń gbé e ṣépè tọmọtọmọ ló ń fi tìbínú-tìbínú sọ̀rọ̀ burúkú sí í. Nígbà tí inú bí ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà Ọba náà,ọ ju ìfọ́tí sí baálẹ̀ lẹnu tó bẹẹ ti itọ́ ṣe fọ́n jáde lénu rẹ̀ wààràwà bíi àhàyá ìbọn.Ó sì pàṣẹ fún un kó dọ̀bálẹ̀ gbàlájà.
Nìgbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Káyọ̀dé Akínmádé ni ohun tó ti ènìyàn lójú ju olè jíjà lọ ní ìwà Táani -yóò -mú -mi ? tí Kábíyèsí náà hù,Ó sì yẹ kó fimú káta òfin.
Ní ti Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Òjó tíí ṣe Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn lórí iroyin ìgbàlódé ó ní ọ̀rọ̀ náà ṣòro í gbàgbọ́ .Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé ó dì dandan kí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ Gómìnà .

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
