
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun láàrin ọdún 1999 sí Ọdún 2003, tó ti tún fìgbà kan jẹ́ alága àkọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ilẹ̀ Nàìjíríà,Olóyè Bísí Àkàndé ti sàlàyé pé Ìjọba Orílẹ̀-èdè yìí lábẹ́ ìsàkóso Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ló gbẹ̀mí Olóògbé Olóyè Bọ́lá Ìgè.
Bisi Àkàndé fẹ̀ṣùn ọ̀rọ̀ yìí kan ìjọba nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè ọlọ́kan-ò-jọ̀kan látẹnu oníròyìn nipa iwé tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí .
Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun yìí ní bí kò bá ní ìdí, obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní onípelejìpele kò tó di pé won pa Bọ́lá Ìgè àti àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́hìn tí wọ́n gba ẹ̀mí arákùnrin náà tán ló di ẹ̀bi ìwà apànìyàn náà lé ìjọba Ọbásanjọ́ lórí.
Fún àpẹrẹ, Àkàndé tẹ̀ síwájú “Bọ́lá Ìgè ṣàdédé pè mí lọ́jọ́ kan tó sì sọ fún mi pé òun yóò kọ ìwé láti fi ipò silẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà labẹ ìjọba Ọbásanjọ́.Kété tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni mo pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ́ Olúwọlé Rótìmí;ẹni tó sọ fún mi kí n gbà á níyànjú pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí tó bá ṣe bẹ́ẹ̀,pípa ni wọn ó pa á.Lóju ẹsẹ̀ náà ni mo sì pè padà tí mo sọ fún wọn.Wọ́n si fún mi lésì pé àwọn ti sọ fún Wọlé Soyinka àti Bọ́lá Tinúbú ti àwọn méjèèjì sì pa ohùn pọ̀ pé kí òun fi ìwé sílẹ̀.Mo ní kó má ṣe bẹ́ẹ̀,ó sì gbà sí mi lẹ́nu”
Alága àkọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ APC ní ohun tó fà á tó fi fẹ́ fi ìwé sílẹ̀ nígbà yen ni àìjẹ́ kí akitiyan rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná ó yọrí sí rere, ìdí sì rèé ti wọ́n fi gbé e lọ sí ọ́ọ́fíìsì Amòfin Àgbà gẹ́gẹ́ bíi Mínísítà ìdájọ́.

Gẹ́gẹ́ bí Àkàndé ti wí,Ó ní olè kìí ja àgbà kó má ṣe é ní ojú fìrí, nígbà tí wọ́n pa Bọ́lá Ìgè tán,Lam Adéṣínà tíì ṣe gómìnà ipinlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà náà gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí kóòtù.Ní kété ti Rasheed Ládọjà sì dé orí àlééfà láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló sì gbé ẹjọ́ náà kúrò ní kóòtù gégé bí àwọn kan ṣe pa á láṣẹ fún ùn .Bárabàra tí a ń sọ ọ̀rọ̀ bàrà ni wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ náà dà di òní olónì-ín.Ìwọ náà rò ó báwo ni wọn yóò ti pa Amòfin àgbà lórílẹ̀ èdè tí a kò sì ní mọ ẹni tó pa á láti iye ọjọ́ yìí?
Ǹjẹ́ Ọbásanjọ́ kó ipa tó yẹ lójúnà láti fi ìyà tó dógbin jẹ àwọn Amòòkùnsìkà tó gbẹ̀mi bàbá náà,Bísí Àkàndé ní “Rárá óò,ìhà kòkànmí ni Bàbá Ìyábọ̀ kọ sí ọ̀rọ̀ náà”
Lórí ìbéèrè wí pé bóyá Iyìọlá Omíṣore ló pa Bọ́lá Ìgè, Àkàndé ni sábàbí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ fún Omíṣore.Òun kò ló pa Bọ́lá Ìgè ṣùgbọ́n ó dájú tó àdá pé ìjọba ló pa ọkọ Atinúkẹ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
