Fún ìgbà Ẹ̀ẹ̀kejì l’ọ́dún 2025; Ójo Rọ̀ Ní Òkìtìpupa

Bi-o-tilẹ̀-jẹ́-pé òjò kò tíì rọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ọdún 2025 tí a, wà yìí, Òjò ti ó rẹ mọ́jú òní ló di ìgbà kejì tí òjò yóò rọ̀ ní ìlú Òkìtìpupa tii ṣe olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.

Òjò to rọ̀ fún bíi wákàtí méjì ọ̀hún lówùúrọ̀ òní kò dé ìlú Òde-aye bí ìlú náà ti súnmọ́ Òkìtìpupa pẹ́kípẹ́kí tó.

Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò àkọ́kọ́ nínú ọdún ló máa ń mú ewu dání pẹ̀lú ìjì àti afẹ́fẹ́ líle ṣùgbọ́n àwọn òjò yìí kò rí bẹ́ẹ̀, wọ́ọ́rọ́wọ́ ló rọ̀ láìmú ewu dání kankan.

inú àwọn ènìyàn pàápàá jùlọ àwọn àgbẹ̀ ló ń dùn pẹlú ìrètí pé bí òjò rírọ̀ bá tẹ̀ síwájú bẹ́ẹ̀, kò ní pẹ́ tí erè oko yóò fi jáde ní ọdún yìí.

Ẹ̀wẹ̀,onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ kan,Ambrose Ikúédùbájiyàn kìlọ̀ fún àwọn àgbẹ̀ pé kí wọ́n ṣọra fún gbígbin nǹkan ọ̀gbìn lásìkò yìí nítorí òjò náà kò ì tíì kárí.

Yàtọ̀ sí Òkitipupa àti agbègbè tí,ó fẹ́rẹ̀ má tíì sí ibòmíràn tí òjò ti rọ̀ tó sì dunlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó l’ọdun 2025 yìí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×