ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ipinlẹ Enugu ti fi páḿpẹ́ òfin gbé òjòwúkùnrin kan Sunday Echege ,ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó ń gbé ní oko Ibagwagu ni Ibagwa -Ani ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Nsukka ní ìpínlẹ̀ Enugu lórí ẹ̀ṣùn pé ó gé ọwọ́ ìyàwó rè nígbà tí ó húhu gbọ́ pé ìyàwó òun, Chinonsu Echege ń yan àlè.
Alukoro àjọ ọlọ́pàá ipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe tó fí ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ní ọ̀daràn náà ti wà ní inú ayanran ìjọba.
Nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn fọ̀rọ̀ jẹ̀wọ̀,Ndukwe ni Sunday sọ pé kìí ṣe pé òun ká àlè mọ́ ìyàwó òun lórí ṣùgbọ́n ẹnu ń kùn ún pé ó ń yan àlè.Ó tẹ̀ síwájú pé kò sí bí òun kò ti tẹ ìyàwó òun nínú tó, kò jẹ́wọ́ pé òun ní ojú níta.Ìbínú èyí ni òun fi gé e ní ọwọ́.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ipinlẹ Enugu,Kanayo Uzuegbu ti pàṣẹ fún igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tó wà fún ẹka ìwà ọ̀daràn láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà.Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní lọ láìjìyà.
Ó wá rọ àwọn lọ́kọ́láya láti máa parí aáwọ̀ yòówù tó bá súyọ nínú ìdílé wọn pẹ̀lú ìfẹ́, Àlàáfíà tàbí nípasẹ̀ òfin yàtọ̀ sí mímú òfin le ara ẹni.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
