Bí ìyàwó Mí Ṣe Kọ̀ Mí Sílẹ̀ dùn Mí Wọ Inú Egungun….Bill Gates


Ọkùnrin tí òkìkí rẹ̀ kàn pé Òun ni ó ní owó jù lọ lágbàáyé tẹ́lẹ̀ ri nnì, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onígbọ̀wọ́ ilé iṣẹ́ Microsoft,Bill Gates ti ṣàlàyé pé bí ẹni fi ìgbọ́nwọ́ sọ ògiri ni kíkọ̀ tí ìyàwó òun Metinda Gates kọ òun sílẹ̀ ní nǹkan bíi ọdún méjì sẹ́yìn ṣe rí.

Ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ ìròyìn The Times ló ti fojú ọ̀rọ̀ yìí léde.Ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta Alówólódù náà ní ìkọ̀sílẹ̀ náà ju òun sínú ìpèníjà tó le koko bí ojú ẹja.Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn bá sì ń ki igi ṣómúṣómú bọ ojú egbò tó ń jinná lọ ló máa ń ri bí òun bá ti ń rántí. Sùgbọ́n Olúwa Òun ti ń gbé e kúrò lára báyìí.

Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù karùn-ún ọdún 2021 ni tọkọtaya náà kéde ìkọ̀sílẹ̀ wọn tí gbogbo ètò ìkọ̀sílẹ̀ si parí nínú osù kẹjọ ọdún náà lẹ́hìn tí wọ́n ti jọ wà pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbáko .

Bill Gates ní Obìnrin gidi ní Metinda nítorí pé ó ni ìfaradà fún òun.Gẹ́gẹ́ bó tí wí, ọdún 1987 ni àwọn méjèèjì pàdé nígbà tí Metinda dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ Microsoft.Bill ti síwájú pé lóòótọ́, òun kìí ṣe Akúṣẹ̀ẹ́ nígbà tí òun pàdé ìyàwó òun ṣùgbọ́n ìbágbépọ̀ àwọn mú ìtẹ̀síwájú tó lọ́ọ̀rìn bá ayé òun.

Nínú ìtẹ̀síwájú tó bá ayé òun ni bí orí ti sọ òun di olówó yalumoyalùmọ̀ tí òun àti Melinda sì dìjọ dá Bill &Melinda Gates Foundation sílẹ̀.Ó ní lára ohun tó dun òun jùlọ ni pé Melinda yọ̀ǹda ilé iṣẹ́ ọ̀hún fún òun.

Bi-o-tilẹ̀-jẹ́-pé ìgbéyàwó àwọn tí forí sánpọ́n,sibẹ̀, ojúṣe àwọn ni ìtọ́jú àwọn ọmọ mẹ́ta tí wọ́n ti tọjú í bọ́ tí Elédùmarè fún àwọn… Jennifer,Rory àti Phoebe.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×