Sọ́ra Rẹ o!Má fi ẹbí Mi Tayín oo…Pọ́tébù fòkò Ọ̀rọ̀ ránsẹ́ sí Ọdúnladé.

Olórin Ṣèwọ́ṣèwọ́ tí ẹnu kìí sìn lára rẹ̀ bìí Afọ́kèéèmù nnì,Abeeb Ọlálọmí ti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ sí Portable ti jáwé akìwọwọ fún ògbóǹtarìgì Òṣèré orí ìtàgé ìyẹn Ọdúnladé Adékọ́lá pé kí ó jáwọ́ nínú àńfẹnu kan Mọ́lẹ́bí òun bí ó bá ń ṣàwàdà nítorí ọká kìí bá ènìyàn ṣe eré gbádìí-gbádìí.

Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń fèsì sí àwàdà tí Adékọ́lá bá ìyàwó rẹ tó ń ṣe eré ìtàgé ṣe pé “Ṣé ọkọ rẹ kò ní fa gádà já bí ó bá gbọ́ pé ó wá sí ìbi eré”

Pọ́tébù ní òun fẹ́ràn Adékọ́lá gidigidi ṣùgbọ́n kó má ṣe mẹ́nu ba ìdílé òun.Òun mọ pé iṣẹ eré ìtàgé ni ìyàwó òun yàn láàyò kí òun tó fẹ́ ẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×