
Ó jẹ́ ohun ìtìjú ńlá gbáà láti rí ọkọ̀ tó dẹrù báyìí lójú pópó wa.Ẹ̀wẹ,kìlómítà méjì ó kéré tán ni àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn ẹ̀sọ́ ojú pópó máa ń to sááfú sí níbi tí wọ́n ti ń ṣe ọrọ̀ ajé wọn nípa gbígba owó ìbọ̀bẹ́ wọn.
Ṣé kí á wá sọ pé òkóbó àwọn ẹ̀sọ́ ààbò ilẹ̀ Nàìjíríà kò bọ ohun tó yẹ kó bọ,igba abẹ́rẹ́ ló le bọ̀ lóòkùn ni àbí dòdò tí wọ́n ti jẹ ló kọ̀ tí kò jẹ́ kí wọ́n le sọ òdodo mọ́.
Kí Olúwa kó jọ̀wọ́ jàre kí ó gbìn ẹ̀mí òdodo sínú gbogbo wa

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
