
Ògbóǹtarìgì Oníṣòwò àti Aláfẹ́ ẹ̀dà ní agbègbè Ẹ̀gbá àti Èkó, Alhaja Khadijat Adébísí Edionseri ọmọ Elégbèdè tí gbogbo ènìyàn mò sí Cash Madam ló tí tẹ́rí gbasọ lọ́jọ́ àìkú ní ilé rẹ̀ ní ìlú Abéòkúta.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi yé wa pé ó tí tó ọjọ́ mélòó kan ti ìyá yìí ti ń wọ̀yá ìjà pẹlú àìsàn kan ti won kò dárúkọ rẹ̀ kó tó di pé ọlọ́jọ́ dé ní àná tii ṣe ọjọ́ karùn-ún oṣù kínní ọdún 2025.
Ebenezer Obey ki màmá yìí nínú ọ̀kan lára àwọn àwo orin rẹ̀ bayii :
“Bísílọlá Edionseri,Cash Madam mi.”
Bákan náà ni Yusuf Ọlátúnjí kì í bayii:
“Ẹ bá mí dúpẹ́ lọ́wọ́ Adébísí, Cash Àníkẹ́ ò ní pàdánù.
Kí Ọlọ́run tẹ́ màmá onífàájì sí afẹ́fẹ́ rere
C

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
