Lọ́dún tuntun: Ah! Gómìnà gba ìjẹ  Lẹ́nu  Àwọn Kan

Akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ àti gbogbo àwọn Kọmísánnà ni wọ́n gba ìwé Gbélé ẹ

Gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa, Abdullah Sule  ti fún gbogbo àwọn ìgbìmò aṣèjọba rẹ̀ ní ìfẹ̀hìntì tipátipá lọ́jọ́ jímọ̀ àná,lẹ́yìn ìpàdé pàjáwìrì tó bá wọn ṣe ní ilé ìjọba ní Lafia ní kété tí igbákejì Ààrẹ Kashim Shetima pẹ̀yìndà tán,nígbà tó parí àbẹwò lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́jọ́ kan  tó ṣe sí ìpínlẹ̀ náà nínú èyí tó ti sí òkan-o-jọ̀kan àkànṣe iṣẹ́ tí ìjọba ìpínlè náà ṣe.

Onímọ̀ Ẹ̀rọ, Abdullah Sule

Kò sí ẹni tó le sọ pàtàkì idí ti ẹ̀bùn ” lọ gbélé ẹ “ Ṣe tọ́ sí àwọn ènìyàn náà nítori kò sí ẹni tó mọ èdè Àyàn bíi ẹní tó mú ọ̀pá rẹ̀ dání.Gómìnà Sule nikan ló le sọ ohun tó fa ìrọ̀nilóyè òjijì náà.

Ní ìbámu pẹlú àlàkalẹ̀ òfin ìjọba,Akọ̀wé àgbà lẹ́ka tó ń mójú tó ìgbìmọ̀ aṣèjọba, Iliyasu Idde ti wá pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn láti jọ̀wọ́ gbogbo dúkìá ìjọba tó wá ní ìkáwọ́ wọn fún akọ̀wé àgbà lẹ́ka kóówá wọn.Nígbà tí Akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún òun.

Ọdún 2021 ni irúfẹ́ ìjì bayii jà tó gbé àwọn Kọmísánnà lọ láti ọwọ́ Gómìnà Sule pẹ̀lú ẹ́ṣùn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn kò já fáfá tó.Ó ti wá fara hàn báyìí pé Sule kìí lo aṣọ kan gbó kó tó pààrọ̀ rẹ̀ nítorí oṣù keje ọdún 2023 ló yan àwọn tí wọ́n ń relé wọn yìí nípò.

Iliyasu Idde wá fẹ̀mí ìmoore hàn lórúko Gómìnà Abdullah Sule sí àwọn Alákòóso náà fún ipa tí wọ́n kó fún ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Nasarawa láàyè kóówá wọn. Ó wá gbàdúrà pé kí Òlọ́run kò ṣe ọ̀nà kálukú wọn níre níbi yòówù tí wọ́n bá dá ẹsẹ̀ tẹ̀.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×