
Yorùbá bọ̀,wọ́n ní “Bí ẹrú bá mọ ìwà í hù, dandan ni kó bá ọmọ dọ́gba àti pé àjèjì tí kò jin onílùú lẹ́sẹ̀ ti rúbọ Ọ̀pẹ́títí . Bí ènìyàn ba wá ń gbà á lérò láti di ọmọ Onílè lókè òkun, ó rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn orile-ede wọ̀nyii ní kété tí ẹ ba ti di àna wọn.
Spain
Bí ènìyàn bá ti fẹ́ ọmọ ni Spain, tó si jáwé Olúborí nínú àwọn ìdánwò ìmọ̀ nípa Èdè ilẹ̀ wọn (DELE A2-language Exam) àti ìmọ̀ nípa àsà (CSSE-Culture Exam). Onítọ̀hùn ti di ọmọ Onílè nìyẹn tí ó bá ti fi ìfẹ́ hàn láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Argentina
Tí ènìyàn bá fẹ́ ọmọ ìlú yìí tí ó sì bí ọmọ fún onítọ̀hùn.Kò lẹ́jọ̀ kò ní àròyé nínú, onitọ̀hún ti di ọmọ Onílè ní Argentina nìyẹn ooo
Brazil
Èdè àti ìgbéyàwó pẹ̀lú ọmọ Onílè ní àtẹ̀gùn sí bí a ti lè rí ìwé tí yóò sọni da ọmọ onílùú gbà.
Italy
Lóòótọ́ ni ìgbéyàwó pẹ̀lú ọmọ Onílè máa ń ṣina láti sọni di ọmọ Onílè ṣùgbọ́n èdè ló ṣe pàtàkì jù nihìn-ín
France
Ọdún mẹ́rin sí márùn-ún tí àjòjì bá ti fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé ni onitọ̀hún yóò tó lẹ́tọ̀ọ́ sí àtisọ ara rẹ̀ dì ọmọ Onílè.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
