
ìjọba fowó kún owó oṣù Àwọn Òṣìṣẹ́
Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ ìsàkóso ààrẹ Bọ́lá Tinúbú fowó kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní bí Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú bu ọwọ́ lu sísan Ẹgbẹ̀rún lọ́ná àádọ́rin náírà fún òṣìṣẹ́ tó ń gba owó oṣù tó kéré jù lọ lẹ́nu iṣẹ ọba.Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ni òṣìṣẹ́ tó ń gba owó tó kéré jù ń gbà tẹ́lẹ̀.

Ìfẹ̀hónúhàn gba ìgboro kan
Tìbú-tòòró orilẹ ede Naijiria làwọn ọ̀dọ́ tí ń fẹ̀hónú hàn tako ìjọba Aninilára.Ní apá Àríwá orile-ede Naijiria ni ìfẹ̀hónú hàn náà ti peléke jù lọ, pàápàá jùlọ ní ìlú Kano.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba náà fẹ̀hónú hàn tako ìjọba
Awọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ wá fọnmú mọ́ ìjọba lọ́wọ́ nípa fífi ẹ̀hónú hàn tako ìjọba lórí bí ohun gbogbo ṣe le koko bíi ojú ẹja.Wọ́n ní oko tó ń jágún kò jágún mọ́,Kọ́léoṣó di Kọ́léẹyẹ,Sàlàkọ́ di Sàlákọ̀.Ìlú le,ebi ń pàlú, ìlú ń kùn.

Orin Orílẹ̀-èdè tuntun
Ní ọdún tó kọjá yìí ni Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú gbé àbádòfin láti yí orin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà padà sí ti àtijọ lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, tí àwọn náà sì bu ọwọ́ lù ú lẹ́yẹ-ò-sọkà.Ọdún 1960 ti Nàìjíríà gba òmìnira ni a ti ń lo orin náà kí ìjọba Ológun lábẹ́ Ọ̀gágun àgbà Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ tóo yíi padà sí “Arise o compatriots” Eléyìí tí a lò títí di ọdún tó kọjá ti ìjọba yìí padà sí “Nigeria,we hail thee,our own dear native land” tí a ń lò báyìí.

Aṣemáṣe àti Ìyọnípo Beta Edu
Ọdún 2024 ni ọ̀kan lára àwọn Mínísítà Tinúbú fi wàdùwàdù lá ọbẹ̀ gbígbóná títí tó fi bó o láhọ́n.Onítọ̀hún ni Mínísítà fún ètò ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn, Arábìnrin Beta Edu tó sọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn di ti ara rẹ nìkan.Gbogbo owó tó yẹ kó bọ́ si àpò ará ìlú ni àwé sọ di tara rẹ̀ nìkan kó tó di pé òkété bórù mọ́ ọn lọ́wọ́.Ràbàràbà rẹ̀ náà ló sì gba ipò náà lọ́wọ́ rẹ̀.

Yahaya Bello àti EFCC
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi àná, Yahaya Bello ń sá kíjokíjo,ó sọ ara rẹ̀ di ìsáǹsá àti Alárìnkiri nítori ẹ̀ṣùn síṣe owó tó tó Àádọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà owó ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi báṣubàṣu tí àjọ EFCC fi kàn án.Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni tàkúté EFCC mún ùn ní àmúbọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ododo tíí ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ṣùgbọ́n ọwọ́ ti padà tẹ̀ ẹ́,ó sì jẹ̀wà fún bíi ọ̀sẹ̀ méjì ní Kuje kí wọn tó gba béèlì rẹ̀ láìpẹ́ yìí.

Àtúntò ìgbìmọ̀ aṣèjọba Àpapọ̀
Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ṣe àtúntò ìgbìmọ̀ aṣèjọba Àpapọ̀.Bi iṣẹ́ ṣe bọ́ lẹ́nu àwọn kan ní àwọn mìíràn di ipò mú.Ṣé bí tẹnìkan kò bàjẹ́ ti ẹlòmíràn kò ní dára.Bianca Ojukwu, tíì ṣe ìyàwó oludasile ogun abẹ́lé ile Naijiria,Odumegwu Ojukwu wà lára àwọn tí ó jẹ Mínísítà tuntun.Inú ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ni Bianca ti wá.

United Arab Emirates gbé ẹsẹ̀ kúrò lórí òfin tó sọ ọ́ di èèwọ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria láti wọ ìlú wọn
Orílẹ̀- èdè United Arab Emirates ti gba awọn ọmọ Naijiria láàyè láti máa wọlé jáde kúrò ní ìlú wọn.O ti tó ọdún mélòó kan ti won ti sọ ọ́ di èèwọ̀ láti gba físà ilẹ̀ náà.

Àtúntò Owó Orí
Ọdún 2024 tó kọjá lọ náà ni ìjọba Àpapọ̀ gbé àbádòfin àtúntò owó orí lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.èrèdii àbá yìí ní láti sọ ìgbà ẹrù àrùwọ́nídìí owó orí ti àwọn mẹ̀kúnnù ń rù kúrò lórí wọn. Awuyewuye sì wà lórí àbá yìí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.

Òmìnira ìjọba ìbílẹ̀
Ọdún mánigbàgbé ni ọdún 2024 jẹ́ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yíká orilẹ ede Naijiria nitori ọdún náà ni òmìnira ìjọba ìbílẹ̀ di òtítọ. Ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ló dá ẹjọ́ ọ̀hún.Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù kìíní ọdún yìí ni ìjọba àpapọ̀ yóò sì ti bẹ̀rẹ̀ àmúlò òfin náà.

Okpebolo di Gómìnà Edo
Ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tó wáyé ní inú oṣù kẹjọ ọdún tó kọjá ló sọ Senétọ̀ Monday Okpebolo ti ṣe ọmọyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC di Gómìnà látàrí bí ó ti fi ẹ̀yìn Alátakò rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Ighodalo gbolẹ̀.

Onyenka Onwenu di Olóògbé
Gbajúmọ̀ Olórin tàka-n-súfèé nnì, Onyenka Onwenu di Olóògbé nibi tó ti ń kọ orin ní ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kan ní ìlú Èkó.Wọ́n gbé é dìgbàdìgbà lọ sí Redington Hospital.Níbẹ̀ náà sì ni ẹlẹ́ran ti tú u lóríṣo.Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin ní í ṣe kí òlọ́jọ́ tó dé bá a láìròtẹ́lẹ̀. Kí Ọlọ́run tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere .

Ìdìbò sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó: Aiyédàtiwa jáwé Olúborí
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrébù Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa jáwé Olúborí nígbà tí ó ti fi ẹ̀yìn Alátakò rẹ̀, Agboọlá Àjàyí họ ògiri gbígbẹ.
Ọjọ́ ketadinlogbon oṣù Kejìlá ọdún 2023 ni Aiyédàtiwa di Gómìnà látàrí ikú Gómìnà, Arákùnrin Rótìmí Ọdúnayọ̀ Akérédolú.Òun náà sì ni òmọyè fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ìdíje náà

Délé Fárótìmí yẹ̀yẹ́ Afẹ́ Babalọlá:Ó ní baba máa ra ìdájọ́ Ni.
Irú ní òun kò tẹ́ rí,àfi ọjọ́ tóí Òun dé Òkèmèsí tí wọ́n pe òun ní eégbọn.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí nígbà tí Délé Fárótìmí kọ ìwé kan nínú èyí tí ó fi tàbùku Alàgbà Afẹ́ Babalọlá pé ọgbọ́n ni baba máa ń ta sí àwọn ẹjọ́ tó ti máa ń jáwé Olúborí.Ó ní bí ẹní ra búrẹ́dì lọ́jà ni baba máa ń ra ẹjọ́ lọ́dọ̀ àwọn Adájọ́.


Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
