Mi Ò Kábàámọ̀ Pé Mo yọ Owó Ìrànwọ́ Orí Èpo… Tinubu

Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú

Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ti sọ yanya pé arọ̀wá kìí wẹ̀yìn ni ìjọba òhun yóò fi yíyọ tí òun yọ owó ìrànwọ́ orí epo ṣe.

Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn fọ̀rọ̀ jẹ̀wọ̀ ni ìlú Èkó. Tinúbú ní èròngbà ìjọba òun ni láti mú ayé rọrùn fún àwọn ọmọ Naijiria.Lóòótọ́,ẹ̀kọ kò ṣe ojú mímu lọ́wọ́ tí a wà yìí fún àwọn ènìyàn látàrí òkan-o-jọ̀kan ìgbésẹ̀ àtúntò tí ìjọba ń ṣe. Ó wá fi dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójú pé dídùn ni ọsàn yóò ṣo láìpẹ́.

Ó ní ohun gbogbo tó lọ sókè ni yóò wálẹ̀ láìpẹ́.Ó ní ìjọba òun kò ní fi ọwọ́ dẹn̄gbẹ́rẹ́ mú ìpèṣè oúnjẹ ní ọdún 2025.

Ní kété tí wọ́n ti búra fún Tinúbú lọ́dún 2023 ló ti kéde ìyọkúrò owó epo, eléyìí tó mú ìnira tí kò lẹ́gbẹ́ bá àwọn ọmọ Naijiria.

Lórí àwọn tó gbé ẹ̀mí mì nitori ètò ìdẹ̀kùn òpin ọdún tí ìyàwó Ọọ̀ni ati Oríyọmí Hamzat ṣe nílùú Ìbàdàn àti èyí tí wọ́n ṣe ní Okija àti Abuja, Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú kẹ́dùn pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àwọn tó di olóògbé.Bákan náà ló yọ ṣùùtì ètè sí àwọn tí wọ́n ṣe agbátẹrù ètò náà fún ṣíṣe ètò tó mẹ́hẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×