Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èrò ní Báǹkì
Kò sí owó ní ATM
Àwọn oní POS ń ta owó fún ará ìlú

Ó dà bí ẹni pé kàkà kí ewé àgbọn rọ̀,koko ló ń le ni ọ̀rọ̀ ara tó ń ni àwọn ọmọ Naijiria pẹ̀lú bó ti ń gba oríṣiríṣi ọ̀nà ṣẹ́ yọ sí wọn.
Èyí tó tún wà níta báyìí ni ọ̀wọ́n gógó owó náírà tó gba ilé gba oko.Bí ó bá tẹ̀ síwájú báyìí, kò sí bí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ rí owó se ọdún kérésìmesì àti ọdún tuntun tó ń bọ̀ lọ́nà yìí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn bánkì ni wọ́n ti fi òté owó péréte bii ẹgbẹ̀rún kan sí mẹ́ta náírà lé owó tí kóówá lè gbà ní bánkì tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ATM kò sì ṣe iṣẹ́.Pabanbarì rẹ̀ wá ni ti àwọn oní POS ti wọ́n ti sọ owó títà di okoòwò wọn
Ìrìnkèrindò Naijanotes yíká àwọn ìpínlẹ̀ bíi Oǹdó, Ọ̀yọ́ àti Kwara fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ṣinṣin pẹlu ìfọ̀rọ̀eánilẹ́nuwò àwọn ènìyàn láwọn ìpínlẹ̀ tí a mẹ́nu bà Òsìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Afijio ní Jóbèlè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Kúnlé Okùnadé í ṣe.Ó ṣàlàyé pé ẹ̀kọ kò ṣojú mímu fún àwọn ènìyàn látàrí ọ̀wọ́n gógó ounjẹ ní pàtàkì jùlọ, owó.Ó ní ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti ń dá ilẹ̀ wa padà sí àkókò Emefiele ti Náírà di imín eégún.Ó wá rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bákan náà ni ọmọ s’orí lọ́dọ̀ Aisha Ibrahim tó ń gbé ní agbègbè Táńkẹ̀ ní ìlú Ìlọrin ní bí ó ti nira fun-un láti rí owó ná lásìkò yìí.Ó ròyìn ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́dọ̀ òní POS tó takú pé Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (₦500) ni òun yóò gbà lórí Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (₦10,000).Ó ní òun ti ṣo ìrìnàjò tí òun fẹ́ rìn sí òkè-ọya rọ̀ dì ọjọ́ mìíràn ọjọ́ọre.
Bánkọ́lé Ògundójútìmí tó ń ṣiṣẹ pẹlu àjọ Àgùnbánirọ̀ sàlàyé ohun tí ojú rẹ rí lọ́wọ́ ọlọ́kọ̀ tó wọ̀ dé Oǹdó lati ìlú Èkó nítori pé Káàsì tí òun kò ní lọ́wọ́ ni dẹ́rẹ́bà fẹ́ gbà.Tipátipá ni òun fi lọ ra Ẹgẹ̀rún mẹwàá ní irínwó náírà lọ́dọ̀ àwọn oní POS.
Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe ń lọ yìí, ohun gbogbo yóò nira fún àwọn ọmọ Naijiria lásìkò Kérésìmesì.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé owó tó tó Tírílíọ̀nù Mẹ́rin ààbọ̀ Náírà ni Báǹkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa ní òhun taari síta kí ọmọ Naijiria lè rí owó lò lásìkò ọdún.
Ogun tó wá kó owó lọ ní ìgboro bayii ni àwọn ọmọ Naijiria kò mọ̀, ṣùgbón àwọn ènìyàn ń na ìka àléébù sí àwọn òṣìṣẹ́ Báǹkì pé wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn oní POS láti máa fi ayé ni àwọn ènìyàn lára.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ìjọba àpapọ̀ ní láti fojú àwọn Afayéninilára lẹ́ka ìgbòkègbodò owó náírà léde kó sì fi ìyà jẹ wọ́n kí ó lé ṣe àṣeyọrí ní ẹka náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
