Ọmọ Ìpínlẹ̀ Kwara ni Ààrẹ ilẹ̀ Ghana Tuntun ; John Mahama.

Yorùbá bọ̀,wọ́n ní ‘ Òǹbíni kò tó Òǹwoni‘ Ìyen ni pé ẹni tó woni ló jẹ́ kí á jẹ́ ènìyàn pàtàkì tí kò gbà wá láàyè láti fi ohun ti a fẹ́ jẹ ba ohun ti a fẹ́ jẹ́ jẹ́. Àwọn àgbà tún tẹ̀ síwájú pé ‘Tìwà-tìṣe la fi ń jọ Alágbàtọ́, tojú-timu la fi ń jọ baba tó bíni lọ́mọ’ Gbogbo àsamọ̀ yìí jẹ́ ti Ààrẹ John Mahama ti ìlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní orílẹ̀-èdè Ghana.

Ọ̀dọ̀ orogún ìyá rẹ̀ tii ṣe ọmọ bíbí ilú Ọ̀fà ní ìpínlẹ̀ Kwara ló gbé dàgbà.Àwọn ni wọ́n tọ́ ọ titi tó fi di àpèwááwò láàrin àwọn ènìyàn.fàlàlà-falala ló le sọ èdè Yorùbá.Kódà,Ọlọ́fà ti ìlú Ọ̀fà fi oyè  Ààrẹ Atọ́láṣe ti ìlú Ọ̀fà dá John Mahama lọ́lá.Ìyẹn túmọ̀ sí pé ọ̀kan lára àwọn olóyè ìlú Ọ̀fà níí ṣe.

Ògbólógbòó Olóṣèlú ni John Mahama tíì ṣe akẹ́kọ̀ọ́gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ghana í ṣe. Ilé ló bá óṣèlú nítorí Olóṣèlú ni baba re lábẹ́ ìsàkóso Ààrẹ Kwame Nkrumah.

Òun fúnra rẹ̀ ti di òkan-o-jọ̀kan ipò òṣèlú mún rí,bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin,titi dé ipò igbákejì Ààrẹ kí orí tó gbé e dé ipò Ààrẹ.

Ìgbà ìkejì sì rée tí yóò jáwé Olúborí gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ tí ìlú dìbò yàn ní orílẹ̀-èdè Ghana.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×