Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó lu àwọn Olóógun lọ́gọ Ẹnu:Ó ní Àwọn Ni Òpó tó di Naijiria Mú

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrébù Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa ti lu awọn ọmọ olóógun ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́gọ ẹnu fún ipa takuntakun ti wọ́n ti kó fún ìdàgbàsókè àti ìṣọ̀kan orilẹ ede Naijiria.

Gómìnà fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi tí ó ti ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ́ḿbúlẹ́mù ti wọn fi ń ṣe ayẹyẹ ìrántí àwọn ọmọ olóógun ti ọdún 2025 tó wáyé ni gbọ̀ngàn kòkó ní ọ́ọ́fíìsì Gómìnà ní Àkúrẹ́ ni ọjọ́ kẹwàá ọdún 2024

Gómìnà ní bí a bá yin ọdẹ, ó yẹ kí á yin apó, bí a bá yin apó, ó yẹ ká yin ọfà, bí a bá sì yin ọfà tán, kí á má saláìyin ojú tí ó sin ọfà dé ọ̀dọ̀ ẹran tí oró fi mẹ́ran.Bí a bá ń yin àwon ọmọ olóógun tó wà níbè báyìí àti àwọn tí wọ́n ti gbébọn ogun tì tó wà láyé, kí á má ṣe aláìyin àwọn tí wọ́n sọ ẹ̀mí wọn nù lójú ìjà, nítorí ìṣọ̀kan ilẹ̀ Nàìjíríà.

Oore tí kò ní àfiwé ni irúfẹ́ oore báyìí.Ẹni ti a bá ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí olósà kóni lẹ́rù lọ ní.Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹ́yìn tí kò lẹ́gbẹ́ fún àwọn mọlẹbi àwọn ọmọ olóógun tó ti sùn lójú ìjà àti àwọn tó kù láyé.

Lẹ́yin èyí,ni Gómìnà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ́ḿbúlẹ́mù náà tí gbogbo awọn yòókù náà sì ń tẹle pẹlu owo tó lówúra.

Inú oṣù kọkànlá ọdún yìí ni wón ṣe Ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe kòkárí ayẹyẹ ìrántí àwọn ọmọ olóógun ti ọdún 2025 . Láti ìgbà náà sì ni igbimo ọ̀hún lábẹ́ àkóso Kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ tó bá jé mọ́ àwọn obìnrin ní ìpínlè Ondó,Díákónì Lọlá Fágbèmí tí ń gbiyanju ní gbogbo ọ̀nà lati ríi pé ayẹyẹ ti ọdún yìí yàtọ̀.

Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kínní ọdún ni orile-ede Naijiria máa ń se ayẹyẹ ìrántí àwọn ọmọ olóógun rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×