Oníwáàsí Àgbáyé Nnì, Muhideen Àjàní Bello ti di olóògbé

Ògbóǹtarìgì Oníwáàsí Àgbáyé Nnì, Muhideen Àjàní Bello ti di olóògbé.Ohun pàtó tó fa ikú olóògbé náà kò ti fi ojú léde.Ẹni ọdún merinlélọ́gọ́rin ni bàbá náà 

Ọdún 1940 ni wọn bí Muhideen Àjàní Bello ní ìlú Ìbàdàn. Ó kan ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa Kùráni,o sì gba ibè di oníwáàsí Àgbáyé.Ó kó ipa takuntakun láti tan ẹ̀sìn islam káàkiri àgbáyé.

Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn oníwáàsí tí a mọ̀ sí Aríbidésí lo túfọ̀ ikú bàbá náà nínú àtẹ̀jáde kan tó gba ìkànnì abẹ́yẹfò X rẹ̀.

Gbogbo àwọn ènìyàn, pàápàá jùlọ ìran Yorùbá kò lè gbàgbé Muideen Bello fún ipa tó kó nínú ìtànkálẹ̀ ẹ̀sìn islam.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×