Owó oṣù tuntun ni àwọn Òṣìṣẹ́ Ipinlẹ̀ Oǹdó yóò fi gbowó Osù kọkànlá….Ọlápàdé

Adelé alága ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Adémọ́lá Ọlápàdé ti fi àwọn òṣìṣẹ́ ipinlẹ̀ Oǹdó lọ́kàn balẹ̀ pé owó oṣù tuntun ni wọn yóò fi san owó oṣù kọkànlá fún wọn.

Ò sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí ní ìlú Àkúrẹ́ nígbà tó n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ohun tó fa pípẹ́ ti owó oṣù kọkànlá àwọn òṣìṣẹ́ ọba ìpínlẹ̀ Oǹdó fi pẹ dírẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, Ó ní Obìnrin tó pẹ́ ní ibalùwẹ̀,aájò ọkọ rẹ̀ náà ló ń ṣe.Idi pàtàkì tí owó náà fi pẹ́ ni kí ìjọba lè ṣe àmúlò owó oṣù tuntun láti fi san owó oṣù kọkànlá.

Ọlọ́pàdé tẹ síwájú pé gbogbo ẹ̀ka oṣiṣẹ tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀  ni yóò gba owó oṣù kọkànlá pẹlú ìṣirò owó oṣù tuntun.

Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwàá ní Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa buwọ́ lu owó oṣù tuntun fún àwọn òṣìṣẹ́ ipinlẹ̀ Oǹdó pẹ̀lú ilèrí pé owó náà yóò di sisan nínú osù kọkànlá.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×