Ní Kwara,Olùkọ̀ dín dùǹdú Ìyà fún Àgùnbánirọ̀:Ó ní kò mọ̀ bí a ti ń kí Ènìyàn

Bí ẹní lu bàrà ní àwọn olùkọ mélòó kan ní ilé ẹ̀kọ́ Government Day Secondary School,Kúléndé, Ìlọrin ṣe lu Àgùnbánirọ̀ kan tí a fi orúkọ bò lásìírí lọ́jọ́ ọjọ́bọ ọ̀sẹ̀ yìí.Lẹ́hìn tí wọ́n dá àjọ ìyá fún un tán ní won tún sọ asọ ẹgbẹ́jọdá rẹ̀ di àkísà mọ́ ọn lọ́rùn.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi yé wa pé ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ní arábìnrin náà ṣẹ àwọn olùkọ́bìnrin náà ni pé kò kí wọn nígbà tí ó ń kọjá lọ láti lọ gba lẹ́tà ‘Mo pegedé láti gba owó oṣù ‘ tí a mọ̀ sí ‘Clearance” ti oṣù kọkànlá.

Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ náà ló kọ́kọ́ kọlù arábìnrin náà kó tó di pé àwọn yòókù ṣùrù bò ó  bíi ìtà bo ẹyìn,tí wọ́n sì lù ú bíi ejò àìjẹ.

Ilé ẹkọ Government Day Secondary School, Kulende, Ìlọrin yìí ni Àgùnbánirọ̀ náà ti ń ṣìnrú ìlú lọ́wọ́lọ́wọ́.

Alukoro àjọ Àgùnbánirọ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara, Ọ̀gbẹ́ni Morákinyọ̀ Ọládiìpọ̀ tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sọ wí pé àjọ náà ti fí ọrọ náà tó ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara létí nípasẹ̀ ilé iṣẹ tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Morákinyọ̀ Ọládiípọ̀ tẹ̀ síwájú pé ilé iṣé àwọn yóò gbé obìnrin Àgùnbánirọ̀ náà kúrò ní ilé ẹkọ náà lọ sí ìbò mìíràn lẹ́yẹ-ò-sọkà.Ó wá kọminú sí ìwà aburú ti àwọn ènìyàn náà hù nítorí ó tako ìwà ọmọlúwàbí tí a mọ àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Kwara mọ́.

Ó ní àjọ Àgùnbánirọ̀ kò ní fi fúúrú lé gbẹ́kẹ́ kí àwọn Kàràm̀bàní ẹ̀dá kan máa ṣe àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin ilẹ̀ baba wọn bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣe ojú láìfi ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n nípaṣẹ̀ òfin.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×