Ẹ pa Olóṣèlú tó bá  jí owó ará ìlú…Jimoh Ibrahim

Sẹ́nétọ̀ Jimoh Ibrahim

Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Gúsù Oǹdó ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní ìlú Abuja ti rọ àwọn Aṣòfin ẹgbẹ́ rẹ̀ láti ṣe òfin tí yóò sọ ọ́ di èèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti lè jí owó ìjọba nípa ṣíṣe òfin ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni yòówù tí aje ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ bá si mi lórí.

Ibrahim fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó n dáhùn òkan-o-jọ̀kan ìbéèrè láti ẹnu àwọn oníròyìn ilé isẹ́ Channel Television lórí òbìtìbítí owó tó tó bílíọ̀nù méjì ó lé igba mílíọ̀nù owó ilẹ̀ Amẹrika ($2.2billion) tí ìjọba Àpapọ̀ fẹ́ yá láti fi ṣe òkan-o-jọ̀kan iṣẹ́ àkànṣe.

Ní ìdáhùn sí ìbéèrè wí pé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Naijiria ti dínkù jọjọ sí ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀yáwó ilẹ̀ òkèèrè nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ irúfẹ́ owó bẹ́ẹ̀ ni àwọn olóṣèlú máa fi ń ṣe ararindin ti yóò sì di gbèsè sí gbogbo àwọn ọmọ Naijiria lọ́rùn, Kín sì ni àmì ìdánilójú pé bí a ti ṣin òkú àná irú ẹ̀yáwó bẹ́ẹ̀ la ó sinkú òní owó tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fi yá yii.Jimoh Ibrahim ní “Ẹ jẹ́ kí n ran ọmọ Nàìjíríà lọwọ ní ìkóríta tí a dé yìí.Ó yẹ kí àwa Aṣòfin  ṣòfin pé bí ẹní pa ajá bọ ògún ni kí wọ́n máa pa ẹni yòówù tó bá ṣe owó ìlú kúmọkùmọ.Ó dájú tó àdá pé bí òfin yìí bá wáyé, oníkálukú á ṣo ewé agbéjẹ́ẹ́ mọ́wọ́ “

Sẹ́nétọ̀ tíí ṣe ọmọ bíbí ilú Igbótako yìí wá ró ìgbàgbọ àwọn ọmọ Naijiria lásọ nípa fí fọwọ́ ṣọ̀yà pé ìjọba Ààrẹ Bọ́lá Tinubu yóò ná owóyàá náà bó ti tọ́ àti bó ti yẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×