Lẹ́hìn Ìdìbò; Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló kù.Ẹ jẹ́ ká dìjọ ṣe ìjọba… Aiyédàtiwa

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ jàwé Olúborí nínú ìdìbò sí ipò Gómìnà tó wáyé ni ìpínlẹ̀ Oǹdó lọ́jọ́ kẹtàdinlogun oṣù kọkànlá ọdún yìí,Họnọrébù Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa ti rọ gbogbo àwọn ènìyàn tó díje pẹ̀lú rẹ láti sọ ọ̀rọ̀ ìbò náà di àfìṣẹ́yìn ti egúngún ń fiṣọ kí wọ́n sì ṣọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti gbé ipinlẹ̀ Oǹdó gòkè àgbà.

Aiyédàtiwa fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń ka àpilẹ̀kọ “Mo gbà” rẹ̀,lẹ́yìn tí wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje tó pegede fi gbọ̀ọ̀rọ̀ jẹkà pẹ̀lú ìbò tó tó Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́fà ó lé Ọ̀rìnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lékan.(366,781). Nígbà tí alátakò rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP,Agboọlá Àjàyí ní ìbò Ẹgbẹ̀rún lọ́ná ọgọ́fà ó dín mẹ́ta ó lé òjìlélẹ́gbẹ̀rin àti márùn-ún (117,845)

Aiyédàtiwa ní ogún àjùmọ̀ni ni ipinlẹ Oǹdó jẹ́ fún gbogbo àwọn, fún ìdí èyí, kí tẹlẹ́rú-tẹlẹ̀mù múra láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òun láti gbé ipinlẹ̀ Oǹdó gòkè àgbà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×