
Láròtẹ́lẹ̀ ni mọ́tò já okùn ẹ̀mí ọkùnrin Ọlọ́kadà kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fàtáì ní Ìlú Bọ́lọ́rundúró tíì ṣe olú ìlú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ìlà oòrùn Oǹdó lọ́jọ́ ajé tó kọjá lọ.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé eré àsápajúdé ni onímótò náà ń sá bi láti ìlú Àkúrẹ́ títí tó fi lọ kọlu ọlọ́kadà náà nibi tó dúró sí tó wó o mọ́lẹ̀ jégéjégé.
Lójú ọgán ni awọn èrò àti Mọ̀lẹ́bí olóògbé ti kán iná lu mọ́tò náà tí wọ́n sì jó o gúdúgúdú.Dírẹ̀ ló kù kí wọ́n jó awakọ̀ náà mọ́ mọ́tò ọ̀hún bí -kò -ṣe ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Àmọ́tẹ́kùn tí wọ́n gbà á lọ́wọ́ ikú tí wọ́n sì fà á lé àwọn Ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Ìwádìí sọ fún wa pé won ti gbé ẹjọ́ náà ló sí olú ilé -iṣẹ́ àwọn olópàá ni ìlú Àkúrẹ́.Won si ti gbé olóògbé lọ sí itẹ́ òkú ìjọba tó wà ní ìlú náà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
