
Àlùfáà ìjọ Oore-ọ̀fẹ́ Baptist church,Ilẹ̀-Olújìí , Àlùfáà Philip Adékúnlé Ọmọ́kanyè ti rọ gbogbo ẹ̀dá alààyè láti máa ṣe àánú fún àwọn ènìyàn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n sì gbà wí pé dandan ní ikú; òhun sì ní agbádá ti ọmọ ènìyàn yóó wọ̀ gbẹ̀yìn.
Àlùfáà Ọmọ́kanyé fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nínú ìjọ náà ní Ilẹ̀ -Olújìí níbi ètò ìṣìn ìkẹyìn tí wọ́n ṣe fún Díákónì Samson Adebayo George,ẹni tó jẹ́ ìpè Ẹlẹ́dàá ní ẹni Ọdún márùnléláàádọ́rin.

Ẹniọ̀wọ̀ Ọmọ́kanyè rọ gbogbo ènìyàn kí wọ́n má ṣe fi ayé ba ọ̀run jẹ́ nitori ìgbà kékeré la ní láti lò ní ayé yìí gẹ́gẹ́ bíi àtìpó àti àlejò nítorí ọ̀run ni ile kóówá wa. Ìríjú Ọlọ́run yìí wá rọ gbogbo àwọn Mọ̀lẹ́bí olóògbé kí wọ́n tújú ká,kí wọ́n má ṣe ba ọkàn jẹ́ rárá nítorí Onígbàgbọ́ òdodo ni bàbá nígbà ayé wọn àti pé ó dájú ṣáká pé Ọ̀run rere ni baba lọ.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ló jẹrìí sí ipa takun-takun ti baba kó fún ìdàgbàsókè ọmọnìyàn àtí iṣẹ́ Olúwa nígbà ayé wọn.Lára wọn ni Àlùfáà Ṣẹ́gun Akínwólémiwá ti ìjọ Sábó Baptist Church, Oǹdó,Díákónì Adégbìtẹ́ ti ijọ Ebenezer Baptist Church, Oǹdó ,Aládùúgbò, Ọ̀rẹ̀,ará àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ètò ìsìnkú náà ń tẹ̀ síwájú lónìí ní ìlú Òtu ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ nibi tí bàbá yóò ti wọ káà ilẹ̀ sùn.Ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọ-ọmọ ló gbẹ̀yin bàbá onínúure náà.
Àwọn ènìyàn pàtàkì láwùjọ bíi òjíṣẹ́ Òlọ́run, Pàràkòyí ìṣòwò, Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àtàwọn èèkàn àwùjọ lọ̀kan-ò-jọ̀kan ló péjú-pésẹ̀ síbi ìṣìn ìkẹyìn náà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
