
Ọ̀gágun àgbà Toheed Lágbájá
Alágbà Tajudeen Lágbájá tíí ṣe àbúrò bàbá olórí ọmọ ogun ilè wa tó di olóògbé ,Ọ̀gágun Taoheed Lágbájá ti sọ pé ikú Ọlọ́run kọ́ ló pa Ọ̀gá àgbà Olóógun tíí tún ṣe ọmọ bíbí ìlú Ìlobùú náà.
Gẹ́gẹ́ bó ti wí, Tajudeen Lágbájá ní èròngbà ọkàn Òun tí Òun fi gbà fọ́ọ̀mù ilé-ìwé gíga jùlọ àwọn ọmọ olóógun ilẹ̀ wa tí a mọ̀ sí Nigerian Defence Academy,Kaduna fún Taoheed ni kí ó ṣe iṣẹ olóógun, kò dàgbà kó dògbó ko sì gbẹ̀hìn tẹ́hìn ṣe fún Òun.Ṣùgbon ikú kò jẹ́ kí èrò náà lè wá sí ìmúṣé.
Baálé ile awọn Lágbájá sọ síwájú pé ikú òjíjí tó pa ọkunrin náà ló jẹ ogun àtilewa, Ṣé bí ikú ilé kò bá pani,tòde kò le pànìyàn. ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí wọn fi kọ́ ilé ìwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn awọn ọmọ olóógun sí ló di ìjà tí wọ́n fi gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ilá ló ń ti ojú olówó rẹ̀ kó, ikàn ló ń tojú olówó rẹ̀ wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀, ìbànújẹ ńlá ni kí màjèṣín ó máa tojú òbí rọ̀run. Àlàgbà Lágbájá ní ìbànújẹ́ ńlá ní ikú ọ̀gá àgbà olóógun náà jẹ́ fún ìdílé awọn ati ìlú Ilobu lápapọ̀

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
