Ààrẹ fẹ́ràn ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́tò
Ó fẹ́ràn kí ó máa wa ara rẹ̀
Kíì sábà ẹnu kù sọ̀rọ̀

Kíì ṣe ìròyìn mọ́ pé bí ẹni lu bàrà ni Ààrẹ Àdìbòyàn ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Donald Trump ṣe lu alátakò rẹ̀ ìyẹn Kamala Haris ninu ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè náà láìpẹ́ yìí.Ní kété tí wón sì ti kéde rẹ̀ bíi òmọyè tó jáwé Olúborí ló sì ti tún tẹnu mọ àwọn ìpinnu rẹ láti mú gbogbo ìlérí tó ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ṣẹ.
Ẹni tó ní òun pa ènìyàn mẹ́fà lójú ogun;Ó délé ó tẹ òròmọdìẹ mẹ́fà pa;Ṣé bójú kò tó tẹ̀gi ṣe kò tó tilé?
Ọ̀sọ̀rọ̀ǹsọbótò bíi tí Báńká Rere ni Donald, Awikonko lójú ọlọ́rọ̀ ni, Pàràkòyí ìṣòwò ni,Ó fẹ́ran ẹ̀ṣìn Kristẹni àti àwọn ènìyàn funfun.Kò sì gba tàwọn ènìyàn dúdú rárá.
Bí inú àwọn kan ti n dùn tí wọn n jó mùkúlú ní inú àwọn mìíràn ń bàjẹ́.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bi lórí Trump ń láìpẹ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
