
Ààrẹ ilẹ̀ America àná tíi tún ṣe olùdíje sí ipò Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Donald Trump ti jáwé Olúborí nínú ètò ìdìbò ilẹ náà tó wáyé lọ́sẹ̀ yii, Ọ̀gbẹ́ni Donald Trump fi ẹ̀yìn Kamala Harish bẹ́lẹ̀ nínú ìdíje náà.Nínú òfíì òhun ọ̀láà ti ọmọ páńdọ̀rọ̀ ń dàgbà ni Trump fi gòkè àgbà dé ipò náà.Òun sì ni Ààrẹ America àkọ́kọ́ tí yóò padà sípò láti nǹkan bíi àádóje ọdún ṣẹ́yìn .
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbègbè bíi Navada,North Carolina, Pennsylvanian àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni Trump ti jáwé Olúborí.
Pẹlu bí àwọn èsì ìbò náà ṣe lọ,o dàbí ẹni pé Ilẹ America kò tíì ṣetán láti yan Ààrẹ tó jẹ́ Obinrin.Ká ní pé Kamala Harish wọlé ni,Óun ní kò bá jẹ́ Ààrẹ àkọkọ tó jẹ́ obinrin ní ilẹ America.
Pàràkòyí ìṣòwò ni Trump,O láyà bí ibọn, kò sí bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ní kọ̀rọ̀ àti ní gbangba.Kii ṣe Alásọkọjẹ ẹ̀dá tàbi Alábúkà méjìpẹ̀lú

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
