
Olórí àwọn ọmọ olóógun orí -ilẹ̀ nílẹ̀ wa, Ọ̀gágun àgbà Taoreed Lágbájá tí di Olóògbé.Àtẹ̀jáde kan tó gba ẹnu Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn sí Ààrẹ Tinúbú , Ọ̀gbẹ́ni Báyọ̀ Ọnànúgà jáde ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde ní ìlú Abuja .
Ó ti tó bíi ọjọ́ mẹ́ta tí òjòjò ti ń ṣògún Jagunjagun náà titi tó fi gbé ẹ̀mí mi ní ilé -Ìwòsàn kan ní ìlú Èkó lọ́jọ́ ọjọ́rùú ọ̀sẹ̀ yìí.
Ìjọba àpapọ̀ wá ti sún ìpàdé awọn aláṣẹ tó ga jù ní ilẹ̀ wa tó yẹ kó wáyé ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ọjọ́ keje oṣù yìí síwájú sí ọjọ́ mìíràn ọjọ́ rere láti fí bu ọlá fún Ọkùnrin náà.
Ọjọ́ kejidinlogun osu Kejì ọdún 1968 ní wọ́n bí Taoreed Lágbájá, ó gba iṣẹ́ olóógun ní ọdún 1987 nígbà tó wọlé sí ilé ìwé gíga jùlọ àwọn ọmọ olóógun ilẹ̀ wa tí a mò sí Nigeria Defence Academy, Kaduna.Ó si jáde gba oyè second lieutenant ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1992.
Ó ti ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Ọ̀gá ní Ọ̀wọ́n kẹta,kejìléláàádọ́rin àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ olú ilé -iṣẹ́ àwọn ọmọ olóógun orí -ilẹ̀.Yàtọ̀ sí èyí,èèkàn pàtàkì ni Lágbájá nínú ìjọ ọmọ olóógun Lafiya D’ole ní Borno,Zaki ní Benue àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà ọdún 2023 ni Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú yan Lágbájá gẹ́gẹ́ bíi olórí àwọn ọmọ olóógun orí ilẹ̀ Nàìjíríà.ipò náà ló sì wà titi tó fi di olóògbé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
