Òpùrọ́ Ni Ọ́;Onítànjẹ Ẹ̀dá Ni Ọ́ Pẹ̀lú…… Aiyédàtiwa fẹ̀ṣùn kan Àjàyí

Gbẹgẹdẹ gbiná níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ti ilé-iṣẹ́ Ìmóhùnmáwòrán Channel Tv ṣe fún àwọn olùdíje sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Gómìnà Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa àti akẹgbẹ́ rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Agboọlá Àjàyí tó wáyé lọ́jọ́ àìkú ọjọ́ kẹta oṣù yìí .

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀, Àjàyí ní Gómìnà Aiyédàtiwa ko múra sí ọ̀rọ̀ ètò àbò ipinlẹ̀ Oǹdó tó, Ó ní ìhà Kòkànmí ni Gomina kọ sí ọ̀rọ̀ náà eleyii tó sì ti fa àìbàlẹ̀ àyà fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Oǹdó.

Olùdíje fún ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní pẹ̀lú owó rọ̀gùnrọ́gún tó tó bílíọ̀nù kan ó lé igba mílíọ̀nù náírà tí Gómìnà ń gbà gégé bí owó ètò àbò lóṣooṣù, kò yẹ kí ètò àbò ipinlẹ̀ Oǹdó mẹ́hẹ tó bó ti ṣe wayii.

Nígbà tí Aiyédàtiwa ń fèsì, ó bi Àjàyí léèrè pé níbo ló ti gbọ́ pé òun ń gba owó tó tó bẹ́ẹ̀ fún ètò àbò;Ó dáhùn pé gbogbo ènìyàn ló mọ̀.Aiyédàtiwa wá ní òun kò mọ ìgbà tí Àjàyí di Olùṣirò owó àgbà ipinlẹ̀ Oǹdó tàbí Kọmísannà ètò ìṣúná tó fi mọ ìyá Ọ̀ṣọ́ ju Ọ̀ṣọ́Àmọ̀tẹ́kùn lọ.O wá ni irú funfun báláú ni Agboọlá ń pa.

Ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀

Ẹnu àwọn méjèèjì kò lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.Gomina ní ibi tí a fẹ́ gbìn obi sí,obì tí hù níbẹ̀ ni àwọn yóò fi ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ṣe nítorí ipinlẹ̀ Oǹdó ti ni Àfarajọ rẹ̀ nínú Àmọ̀tẹ́kùn tí Gómìnà àná, Rótìmí Akérédolú dá sílẹ̀.Ní tiẹ, Àjàyí ní kókó ni ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ nitori ohun nikan ni ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú kọ̀bà-ò-le ètò ọrọ̀ àbò tí ilẹ̀ yìí wà.

Ìpèsè Iṣẹ́

Àjàyí fojú láìfí wo ìjọba ìpínlẹ̀ Oǹdó lábẹ́ àkóṣo Aiyédàtiwa ni bi kò ti pèṣè iṣẹ́ fún àwọn ẹgbẹlẹmòkun ọ̀dọ́ ipinlẹ̀ Oǹdó. Ó wá ní òun ṣetán láti pèsè isẹ́ lọ̀pọ̀ yanturu fún àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ Oǹdó.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×